Guinea : Ìdí tí ìdìtẹ̀ gbàjọba Ààrẹ Alpha Conde ṣe wáyé ní Guniea

Àwọn ológun gbàjọba ní orílẹ̀-èdè Guinea

Oríṣun àwòrán, Guinea Tv

Awọn ologun ni orilẹ-ede Guinea ti gba ijọba nilẹ naa.

Iditẹgbajọba ti wo ijọba Ààrẹ Alpha Conde lulẹ.

Ọpọ ọmọ orilẹ-ede Guinea ni inu wọn kò dùn sí ijọba Aarẹ Conde lẹyin to wọlé fun saa kẹta ní bii ọdún kan din diẹ sẹyin.

Rogbodiyan bẹ sílẹ lẹyin ti Conde wọle tan, ẹgbẹ alatako naa kọju ìjà sí ijọba Conde.

Ile iṣẹ ologun gbe Conde, ẹni ọdun mẹtalelọgọrin sí àhámọ́ lẹyin ti awọn eeyan gburo ibọn lẹgbẹ ile iṣẹ aarẹ ni Conakry.

Ọgagun GFS, Mahamady Doumbouya lo Kede lori ẹrọ amohunmaworan le awọn ologun ti gba ijọba.

Ọgagun Doumbouya ṣèlérí pé àwọn ologun yóò ṣètò lati gbe ijọba fún alágbádá.

O ni omi tuntun ti ri, ẹja tuntun Si ti wọọ lori ìṣèjọba orilẹ-ede Guinea bayii.

Ajọ AU, UN ati ECOWAS naa ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ awọn ologun ni Guinea.

Awọn yii fẹ ri pe awọn ologun gbe ijọba padà fún alágbádá ni kiakia.