Taliban take-over: Taliban láwọn ti gba ẹkùn Panjshir, NRF ní irọ́ ni

Taliban take-over: Taliban láwọn ti gba ẹkùn Panjshir, NRF ní irọ́ ni

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ẹgbẹ Taliban to gba ijọba orilẹ-ede Afghanistan ti kede pe awọn ti gba ẹkùn Panjshir to n fi apa janu lori bi Taliban ṣe gba ijọba.

Awọn ọmogun Taliban ti fìjà pẹta ni ẹkùn náà tó wà ní apa Ariwa ilu Kabul pẹlu ẹgbẹ NRF to n tako ijọba Taliban.

Agbẹnusọ ni Afghanistan ti bọ lọwọ ogun lẹyin ti Taliban gba ẹkùn Panjshir tan.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Kò sí ìdí tí à ó fi bínú sí Akeredolu lórí ọ̀rọ̀ Yorùbá Nation

Ṣugbọn ẹgbẹ NRF ti sọ pe irọ nla ni ẹgbẹ Taliban n pa.

Agbẹnusọ NRF, Ali Maisam sọ fún BBC pe ko di òtítọ nínú ọrọ ti Taliban sọ lori ẹkun Panjshir.

Awọn fọto kan n ṣe afihan ọm'ogun Taliban ní iwaju ile gomina ẹkun naa, àmọ́ BBC ko tii le fi idi rẹ múlẹ.

Lọsẹ mẹta sẹyin ni Taliban gba jọba lorilẹ ede Afghanistan.

Adari ẹgbẹ NRF, Ahmad Massoud sọ pe òun ṣetan lati ṣe ijiroro àlàáfíà lọjọ Aiku.

Ọgbẹni Massoud ni oun faramọ erongba awọn olori ẹsin to pe fún asọyepọ.

O kepe ẹgbẹ Taliban lati dẹkun iwa ipa to n hu.

Ṣugbọn Taliban ko tii fesi lori ọrọ naa.

Eeyan bi ẹgbẹrun lọna igba lo gbe ni ẹkun Panjshir to wa ni isalẹ awọn òke.

Ẹkun Panjshir yìí naa lo tako ijọba Soviet Union ni nkan bi ogoji ọdun sẹyin.

Bakan naa ni ẹkun Panjshir yìí tún tako ijọba Taliban láàrin ọdún 1996 sí 2001.

Adari ẹgbẹ NRF meji niwọn ṣeku pa lọjọ Aiku.

NRF ni wọn ti pa agbẹnusọ oun, Fahim Dashti ati ọgagun kan, Abdul Wudod Zara.

Àmọ́, ọgagun Taliban kan ati iṣọmọgbe rẹ mẹtala naa tẹri gbaṣọ.