JOHESU fún ìjọba Nàìjíríà ní gbèdéke ọjọ́ 15 ṣáájú ìyanṣẹ́lódì, kà nípa nkán tí wọ́n n béèrè fún

Awọn dokita to n ṣe iwọde

Oríṣun àwòrán, others

Agbarijọpọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ẹka eto ilera ni Naijiria JOHESU ti fi gbendeke ọlọjọmẹẹdogun lelẹ fun ijọba Naijiria lori sisan awọn gbese owo ajẹmọnu wọn.

Wọn ni bi ijọba ba kọ ti ko san owo yii, awọn yoo gun le iyanṣẹlodi ọlọjọgbọọrọ.

Aarẹ ẹgbẹ naa Biobelemonye Josiah, lo fidi ọrọ yi mulẹ ninu iwe kan to kọ si Minisita feto igbanisiṣẹ Naijiria Chris Ngige ati awọn alẹnulọrọ mii nilu Abuja lọjọ Abamẹta.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Naijiria kan This Nigeria ṣe jabọ, Josiah ni gbendeke ọlọjọmẹẹdogun yi di dandan nitori aikọbiara si awọn ẹdun ọkan wọn lati ọdọ ijọba apapọ.

O ka awọn orisirisi ọrọ to niṣe pẹlu ajẹmọnu oṣiṣẹ ti ijọba kuna lati sọ to fi mọ ajẹmọnu lati ọdun 2014, owo oṣu oṣiṣẹ ti ijọba di mọwọ ni 2018 ati awọn owo aabo fawọn oṣiṣẹ nitori Covid-19.

Aarẹ JOHESU ni ijọba ko tiẹ fesi si iwe tawọn kọ lẹyin ti wọn buwọlu adehun lati oṣu Kẹsan ọdun 2017.

''Gbogbo ẹyin oṣiṣẹ wa, a fẹ ki ẹ wa ni ṣẹpẹ de aṣẹ lati gunle iyanṣẹlodi bi awọn ijọba ko ba fesi si awọn ẹhonu wa.''

O sọ pe bẹrẹ lati oru ọjọ Kẹtadinlogun oṣu Kẹsan awọn oṣiṣẹ to wa labẹ aṣia JOHESU yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi ni gbogbo awọn ile iwosan ijọba ibilẹ ati ipinlẹ jakejado Naijiria.

Titi di igba ta fi n ṣe akojọpọ iroyin yi, ijọba apapọ Naijiria ko ti fesi si ọrọ yi.

Ileewosan nla UCH

Lọwọlọwọ bayi, awọn dokita to wa lẹnu ikọṣẹ lawọn ileewosan jakejado Naijiria ta mọ si Resident Doctors wa lẹnu iyanṣẹlodi.