Resident doctors strike in Nigeria: Ẹgbẹ́ àwọn dókítà àti ìjọba tako ara wọn l'Oyo lórí ìyanṣẹ́lódì

Doctors

Oríṣun àwòrán, @BBCAfrica

Ẹgbẹ awọn dokita ipinlẹ Oyo ti sọ pe ko si ootọ ninu ọrọ kan ti ijọba ipinlẹ naa n sọ pe awọn ko daṣẹ silẹ.

Ṣaaju ni kọmiṣọna fun eto ilera ipinlẹ ọhun, Bashir Bello ti kọkọ sọ fun BBC Yoruba pe awọn dokita ipinlẹ ọhun ko gunle iyanṣẹlodi kankan .

Bello sọ pe gbogbo ohun ti awọn dokita n bere lọwọ ijọba ipinlẹ Oyo ni ijọba naa n ṣe fun wọn, eyii to mu ki ajọṣepọ to wa laarin wọn gun rege.

O ṣalaye pe nitori naa ni awọn dokita naa ko ṣe darapọ mọ awọn akẹgbẹ wọn to n daṣẹsile ni Naijiria.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, "eto ilera ṣe patakli si ijọba to wa lode yii, nitori naa ko si dokitan kankan nipinlẹ Oyo to daṣẹsilẹ, a si n tọju awọn iba perete to n ṣiṣẹ lawọn ile iwosan ijọba."

"Lasiko ajakalẹ arun Corona yii gan, obitibiti owo ni gomina ipinlẹ Oyo la kalẹ fun ile iwosan UCH, eyii to n ṣafihan awọn anfani ti awọn eeyan n jẹ lara ijọba, nitori naa ni wọn ko ṣe ni eredi kankan lati da iṣẹ silẹ."

Ṣugbọn nigba ti BBC Yoruba kan si Aarẹ ẹgbẹ awọn dokita nile iwosan ijọba apapọ to wa niluu Ibadan, UCH, dokita Zakariyau Temitope Hussein ni irọ pata ni ọrọ ti ijọba sọ nitori awọn wa ni iyanṣẹlodi.

Hussein sọ pe awọn ti yanṣelodi gẹgẹ bi awọn akẹgbẹ awọn kaakiri Naijiria, bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ awọn dokita miran n ṣiṣẹ lọ lọwọ.

O ni "awa resident doctors ti daṣẹ silẹ o, ṣugbọn awọn dokita miran ti wọn n pe ni 'consultants' ṣi wa lawọn ile iwosan."

Àkọlé fídíò, Àwọn èdè abẹ́ ahọ́n tóo lè fi sọ̀rọ̀ rèé láì tú àṣírí ọ̀rọ̀ rẹ áyé

Hussein sọ siwaju sii pe "awọn ọmọ ẹgbẹ wa ni UCH ati ile iwosan to wa ni LAUTECH ti yanṣelodi, emi o mọ ohun ti kọmiṣọna fun eto ilera n sọrọ nipa rẹ."

Ẹgbẹ awọn dokita naa gunle iyanṣẹlodi kaakiri Naijiria lẹyin ti wọn fẹsun kan ijọba apapọ pe o n fi awọn ẹtọ wọn dun wọn.

Bakan naa ni wọn tun n bere awọn ajẹmọnu kan to yẹ ki ijọba fun wọn lasiko ajakalẹ arun Covid-19, ṣugbọn wọn ni ijọba kọ etin ọgbọin si awọn ibere wọn.

Àkọlé fídíò, Jimoh Ológì déé! Ọ̀mọ̀wé ní kílàsì fásitì, ológì nílé