Genesis Global: Ìwádìí rèé lórí ìdí tílé ẹjọ́ fi gba onídùróó Wòlìí Genesis lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

Israel Oladele Ogundipe Genesisi

Oríṣun àwòrán, Genesis Global

Ileẹjọ kọtẹmilọrun nipinlẹ Eko ti gba beeli adari ijọ CCC Genesis Global, Israel Ogundipe lẹyin oṣu mẹrin ni ọgba ẹwọn.

Woli Genesis ni wọn fi silẹ ni Ọjọ Kini, Oṣu Kẹrin, ọdun 2021 lasiko igbẹjọ rẹ to waye ni ọjọ naa.

Ileẹjọ giga nipinlẹ Eko lo ran an lọ si ẹwọn ọdun kan pe, o jẹbi ẹsun gbigba ohun ini Arabinrin Olaide Williams-Oni, towo rẹ to miliọnu mẹtadinlogun naira, pe ohun fẹ ba a ra ilẹ.

Àkọlé fídíò, Mobile Wash: iṣẹ́ fífọ́ mọ́tò tà ni mó yàn láààyò- Slay Mama

Woli Genesis ni ko fara mọ idajọ naa, ti wọn si tẹsiwaju lọ si ileẹjọ kotẹmilọrun.

Amọ wọn ti gba beeli rẹ pe ki o ma a wa fun igbẹjọ rẹ lati ile titi ti ileejọ kotẹmilọrun yoo ṣedajọ rẹ.

Se lootọ ni Genesis Global ní Diabetes ní wọ́n ṣe tusilẹ ní ẹ̀wọ̀n?

Israel Oladele Ogundipe

Oríṣun àwòrán, Twitter/Israel Ogundipe

Ọpọlọpọ iroyin lo ti jade lori bi Isreal Ogundipe ṣe gba itusilẹ lẹwọn lai tii lo akoko rẹ tan ni ọgba ẹwọn.

Awọn iwe iroyin kan gbe e pe, nitori ailera ara rẹ ni wọn ṣe fi silẹ ni ọgba ẹwọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ati wi pe agbẹjọro rẹ, Babatunde Ogala (SAN) lasiko igbẹjọ wi pe, o ni aisan suga, ti ko si raye gba itọju to peye ni ọgba ẹwọn, ni wọn ṣe fi silẹ.

Amọ, agbẹnusọ ile ijọsin Celestial Church of Christ, Genesis Global, Gbolahan Ashorobi sọ fun BBC Yoruba pe ko si otitọ kankan nitori iroyin pe ilera rẹ ni ko dara to.

Ashorobi ni saka ni ara rẹ da, ko si ni aisan kankan to n ṣe e.

Kini idi ti ileejọ fi gba beeli Genesis Global?

Genesis Global

Oríṣun àwòrán, Facebook/Genesis Global

Agbẹnusọ ile ijọsin, CCC Genesis Global, Gbolahan Ashorobi ni idi mẹta ni ileẹjọ fi silẹ, ki wọn to gba oniduro Wolii Ogundipe.

O ni idi akọkọ ni nitori igbagbọ ti wọn ni ninu rẹ wi pe ko le e salọ ki igbẹjọ rẹ to bẹrẹ ni ileẹjọ.

O salaye pe ileẹjọ fi silẹ nitori igba akọkọ niyii ti yoo ṣẹ si ofin ati wi pe, ilumọọka ni ti ko le e salọ ni ilu nitori gbogbo igba igbẹjọ rẹ, lo n lọ si ileẹjọ.

O tun fikun pe adajọ salaye wi pe ọpọlọpọ ẹjọ lo wa ni iwaju ileẹjọ kotẹmilọrun, nitori naa, wọn ko le e fi awọn ẹjọ to wa niwaju wọn silẹ ma a da ẹjọ Genesis Global.

Àkọlé fídíò, Pure Water Lylon Art: Adejoke ní ohun èlò ta fi ọ̀rá ṣe ń ní àlòpẹ́, kìí tètè jẹ

Adajọ ni tawọn ko ba gba oniduro r bayii, o le e lo gbogbo ọjọ to yẹ ko lo ni ẹwọn tan, ki igbẹjọ to kan an nile ẹjọ Kotemilorun.

Agbẹnusọ fun ijọ Genesis fikun pe ni ileẹjọ salaye wi pe yoo jasi ifiyajẹni lori asan to ba jẹ wi pe, ileẹjọ ṣe iwadii wọn, ti wọn si ri pe o ti lo ọdun kan ni ẹwọn lai jẹbi.

Ashorobi ni nitori naa ni wọn ṣe gba beeli rẹ pẹlu oniduro meji, milọnu meji naira pẹlu awọn ohun ini ilẹ.

Bakan naa ni agbẹnusọ naa sọ wi pe, awọn alaṣẹ ijọ naa yoo ba awọn akọroyin sọrọ ni Ọjọ Isinmi, Ọjọ Kẹrin, Oṣu Kẹrin, ọdun 2021 lati se alaye ọrọ naa lẹkunrẹrẹ.