Don Jazzy wife: Ìgbéyàwó mi túká nítorí iṣẹ́ orin ni mò ń fi gbogbo àkókò mi fún

Oríṣun àwòrán, donjazzy
Gbajugbaja olorin ọmọ Naijiiria, Don Jazzy ti ṣalaye pe bo ṣe ṣegbeyawo ni nnkan bii ọdun mejidinlogunsẹyin ṣugbọn ti igbeyawo naa tuka.
Don Jazzy lo sọ ọrọ naa loju opo Instagram rẹ, nibi to ti sọ pe ọmọ ogun ọdun pere ni oun lasiko naa ki oun ati iyawo oun ọhun to pinya nigba ti oun wa ni ọmọ ọdun mejilelogun.
Nigba to n sọrọ lori bo ṣe ṣẹlẹ, oludari ileeṣẹ Marvin Records naa ṣalaye pe ifẹ ti oun ni si iṣẹ orin lo da ifẹ oun ati iyawo oun, Michelle Jackson, to n fi ilẹ Gẹẹsi ṣebugbe ru.

Oríṣun àwòrán, donjazzy
O ni "fun ọpọ igba lawọn eeyan ti maa n bere lọwọ mi pe igba wo gan ni mo fẹ gbe iyawo, ṣugbọn ootọ ibẹ ni pe mo ṣe igbayawo ni nkan bii ọdun mejidinlogun ṣeyin nigba ti mi mo wa lọmọ ogun ọdun pere."
"Mo gbe ọrẹ mi atata, Michelle niyawo, o si larinrin, ṣugbọn mo fi ayọ fọ nitori iṣẹ orin ni mo n fi gbogbo akoko mi gbọ."
Don Jazzy ni ituka igbeyawo ọhun dun oun pupọ, ati pe oun ṣi ni ifẹ si orin kikọ, nitori naa oun ko ṣetan lati ṣe igbeyawo miran eyii ti yoo tun tuka nitori bi oun ṣe n fi gbogbo akoko oun gbọ ti iṣẹ orin.
O ni bo tilẹ jẹ pe oun ko fẹran lati maa ṣorọ nipa ọrọ ifẹ oun ni gbangba, ṣugbọn oun sọrọ naa jade lẹyin ti oun wo ifọrọwerọ kan, Bounce, ti Ebuka wa ninu rẹ.
Ọpọ awọn ololufẹ Don Jazzy lo ti n fi erongba wọn lede lori aṣo to ṣi loju eegun yii.












