Olusegun Obasanjo àti Sheikh Gumi ṣe ìpaàdé lórí ètò àbò Naijiria tó mẹ́hẹ l'Abeokuta

Obasanjo and Gumi

Oríṣun àwòrán, OOPL

Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Olusegun Obasanjo ati gbajugbaja ẹlẹsin Musulumi Sheikh Ahmad Gumi ti ke si ijọba apapọ lati ṣe agbekalẹ ile ẹjọ pataki ti yoo maa gbọ ẹjọ awọn janduku, awọn ajinigbe atawọn to n lo ibọn lai gba aṣẹ.

Wọn tun sọ pe ki ijọba ṣe atunsẹ igbeaye awọn ọdaran ti wọn ba ronupiwada, ki wọn si fun wọn ni ẹkọ ati iṣẹ ti wọn yoo maa ṣe dipo iwa ọdaran.

Obasanjo ati Gumi lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade ti awọn mejeji buwọlu lẹyin ipade ti wọn ṣe nile Obasanjo to wa niluu Abeokuta.

Ninu atẹjade naa to ni koko mọkanlelogun ni wọn tun ti rọ ijọba apapọ lati fi ọrọ eto abo Naijiria to mẹhẹ to ajọ ilẹ Afrika leti iyẹn, ECOWAS.

Obasanjo ki Gumi fun akitiyan rẹ lori eto abo loye ọya, bẹẹ naa ni Gumi gbe oṣuba kara fun Aarẹ tẹlẹri ọhun fun awọn ipa to ti sa sẹyin ki Naijiria le dara.

Obasanjo and Gumi

Oríṣun àwòrán, oopl

Bakan naa ni wọn tun gba ijọba ni imọran lati maa dabo bo awọn amí to ba n fi ọrọ awọn ajanduku naa to ijọba leti, ko si tun maa ṣe iwuri fun wọn.

Lara awọn koko naa ni "ki ijọba maa fi iya to tọ jẹ awọn ọdaju ọdaran, ko ma si fi oju aanu wo gbogbo awọn to n gbe ibọn kiri lai gba aṣẹ to yẹ."

Àkọlé fídíò, Àṣírí ìdí tí ìjínigbé fi ń ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà ló tú nínú fídíò yìí

"Ki ijọba tun ṣe agbekalẹ awọn ile ẹjọ pataki ti yoo maa gbọ ẹjọ awọn janduku, ajinigbe, awọn to n gba owo itusilẹ lọwọ ẹbi awọn ti wọn ji gbe, atawọn to n gbe ibọn kiri lọna aitọ."

Obasanjo and Gumi

Oríṣun àwòrán, oopl

Atẹjade naa pari pẹlu imọran pe ojuṣe gbogbo ọmọ Naijiria ni eto abo jẹ.

Lẹyin naa lo ni awọn memeji ti fẹnuko lati wa ọna abayọ si eto abo Naijiria to mẹhẹ, ati pe Sheik Gumi ti fi iwe pe Obasanjo lati bẹ ilu Kaduna wo lati tẹsiwaju ninu ijiroro wọn.

Àkọlé fídíò, Pure Water Lylon Art: Adejoke ní ohun èlò ta fi ọ̀rá ṣe ń ní àlòpẹ́, kìí tètè jẹ