Missing Alpha Jet: Ayédèrú fídíò ni Boko Haram fi léde lórí ọkọ̀ òfúrufú ọmọgun Alpha Jet tó pòórá -NAF

Ọkọ ofurufu to poora

Oríṣun àwòrán, NAF

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn onimọ nipa eto abo ti sọrọ lori baalu ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu to poora ni Maiduguri, eyii ti ikọ ẹgbẹ agbesumọmi Boko Haram sọ pe awọn lo jaa bọ.

Ninu atẹjada kan ti ileesẹ ọmọ ogun fi lede, wọn ni ofege ni fidio ti Boko Haram gbe jade lori bi wọn ṣe ja baalu naa bọ.

Wọn ni ko si ootọ kankan ninu fidio naa, ati pe ki awọn ọmọ Naijiria ma ṣe ka fidio naa si.

Ṣaaju ni ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu, NAF, ti kọkọ kede pe baalu naa, to ni nọmba idanimọ NAF 745 ti poora, ati pe iwadii ti bẹrẹ lati mọ bo ṣe rin.

Onimọ kan nipa eto abo, Audu Bulama Bukarti to n ṣe iwadii nipa eto abo l'Afrika sọ fun BBC pe, fidio ti Boko Haram gbe jade ko le jẹ otitọ nitori bi wọn ṣe ge fidio naa nigba mẹta ọtọtọ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Onimọ naa wa ni o ṣeeṣe ki Boko Haram mọ ibi ti baalu naa ja si, ki wọn si tete de agbegbe naa lati ya fidio rẹ lasiko ti awọn ọmọ ologun ṣi n wa lọwọ.

Àkọlé fídíò, Pure Water Lylon Art: Adejoke ní ohun èlò ta fi ọ̀rá ṣe ń ní àlòpẹ́, kìí tètè jẹ

Audu fi kun pe ewu n bẹ loko longẹ Naijiria to ba jẹ pe lootọ, ọkọ baalu ti ileeṣẹ ologun n wa ni eyii ti Boko Haram sọ pe awọn ja lulẹ.

Skip Facebook post, 1

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post, 1

O fi kun pe "ko ni jẹ iyalẹnu to ba jẹ pe Boko Haram lo ja balu naa bọ nitori misaili kan ti ikọ naa yin loṣu to kọja balẹ si aarin ilu Maiduguri, eyii to mu ẹmi eeyan mẹrindilogun lọ, lara awọn ti ọmọ wẹwẹ mẹsan an wa."

O pari ọrọ rẹ pe ijọba Naijiria ni lati gba pe awọn ọmọ ẹgbẹgun Boko Haram ni ohun ija oloro lọwọ, ki ijọba si ṣe ohun to yẹ lati ri pe awọn ọmọ ogun rẹ naa ni ohun ija to lagbara lati koju awọn ọmọ ogun Boko Haram ọhun.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Ó ṣeéṣe kí ọkọ̀ òfúrúfú ọmọgun Alpha Jet tó pòórá tí já - NAF

Ọkọ ofurufu to poora

Oríṣun àwòrán, NAF

Ilé iṣẹ́ ọmọ ogun ojú òfurufú ti ni ìwòyé ìwádìí àwọn fi hàn pé, ọkọ̀ òfurufú Alpha Jet (NAF475) tó pòórá kúrò lójú ìwòràn ilé iṣẹ́ náà, seese ko ti ja lulẹ.

Awọn ọmọ ikọ̀ ologun ojú òfurufú méjì lo wà nínú ọkọ ofurufu naa eyi to poora loju ofurufu lọjọru.

Kò sí àrídájú ǹkan tí ó fa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tàbi ibi tí àwọn ologun méjì náà já sí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn awakọ̀ òfurufú náà ni Ọgagun ofurufu John Abolarinwa àti Ebiakpo Chapele.

Skip Facebook post, 2

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post, 2

Adarí ìpolongo àti ọ̀rọ̀ tó n lọ fún ilé iṣé ọmọ ogun ofurufu, Edward Gabkwet, lo sisọ loju ọrọ naa ninu àtẹ̀jáde kan to fisita.

O sàlàyé pé, gbogbo àwọn ikọ ọmọ ogun, tó fí mọ́ àwọn ọmọ ogun orí ilẹ̀, ló n ṣaayan lọ́wọ́lọ́wọ́ bayii lati ṣe àwárí àti ìdóòlà ẹ́mí àwọn ènìyàn náà.

Wọ́n fi kún pé, pẹ̀lú bi ǹkan ṣe lọ yìí, kò sí ǹkan ti kò le ṣẹlẹ̀ sùgbọ́n àwọn ni ìrètí pé ó yẹ kí wọ́n rí àwọn méjì náà láti dóòlà wọn.

Ó ṣeéṣe kí ọkọ̀ òfúrúfú ọmọgun Alpha Jet tó pòórá tí ni ìjàmbá-NAF

Oríṣun àwòrán, NAF

Ọ̀sán ọjọ́bọ ọjọ́ kíní, oṣù kẹrin ọdún 2021 ni NAF kéde pé àwọn kò rí Alpha Jet mọ́ láti aago márún kọjá ìṣẹ́jú mẹ́jọ lọ́jọ́rú.