Cattle Ranching: Ẹ wo Fulani darandaran to tako àṣà dída màálù kiri lójú pópó

Àkọlé fídíò, Cattle Ranching: Ẹ wo Fulani darandaran to tako àṣà dída màálù kiri lójú pópó

Oniruuru awuyewuye lo ti n waye nitori bi awọn darandaran se maa n da ẹran laarin igboho ati oju popo yika orilẹede Naijiria.

Koda, nitori awọn ewu to n ti idi ẹran dida yika igboro jade, ni ọpọ ijọba ipinlẹ se fi ofin de asa dida ẹran kiri oju popo, ki eto aabo to peye le wa.

Amọ ọkunrin kan ree, Azzez Abdul ti ilana ọsin ẹran dida rẹ ba ti igbalode mu, ti ko si yan asa atijọ dida ẹran kiri ilu laayo.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Abdul tii se ọlọsin ẹran maalu salaye pe o tẹ oun lọrun lati maa sin ẹran toun ninu ibudo ọsin ẹran, ju ki oun maa da ẹran kiri lọ.

Darandaran igbalode naa, ti awọn baba nla rẹ jẹ ẹya Fulani, mẹnuba awọn iriri rẹ ninu ilana ọsin ẹran nilana igbalode ati ọpọ anfaani to wa ninu rẹ.

Abdul Azeez ati Fulani to n ba mojuto ọsin ẹran naa tun mẹnuba awọn anfaani iriri latọdọ Fulani to yan ọsin ẹran laayo.