Elega Village Poor Water: Wo ìlú tí èèyan àti àgùntàn, màálù ti ń pín omi kanṣoṣo mu
Ọrọ Yoruba to maa n ni omi la bù wẹ̀ omi la bù mu a kii ba omi ṣe ọta fẹ ṣe bakan ni ilu elega ni ipinlẹ Kwara o tori wọn o ri i bu wẹ bu mu.
Ilu ti wọn ti ko aja pọ mọ ẹran leleyii o lori ọrọ omi toripe ati eniyan, "ataguntan, ati maalu, baa ṣe jọ n mu u niyẹn". Eyi ni arabinrin kan sọ.

Bẹẹ, orisun omi kanṣoṣo ti wọn ni ilu yii niyii. Koda itan to rọ mọ ọ ti wọn ni awọn baba nla awọn sọ fun awọn ni pe latigba ti wọn ti tẹ ilu Elega do ni wọn ti bẹrẹ si ni gbẹ oju iho omi yii wọn si tun fi le awọn ọmọ wọn naa lọwọ pe ki wọn tubọ maa gbẹ ẹ si i bibẹẹ kọ omi o le sun jade taara.
Awọn ara ilu yii kigbe sita pe awọn n wa iranwọ tori iṣoro omi mimu ti wọn n koju.
Ọpọlọpọ iṣoro ni aini omi yii n fa fun wọn to si n pa iṣẹ ọwọ ọpọlọpọ lara to bẹẹ ti awọn eeyan ti igbe aye ilu naa ko ba lara mu n sa lọ si ilu Ilorin atawọn ilu mii.
"Àwọn míì tó wọ ìlú tilẹ̀ ní àwọn ò lè máa bá wa gbé máa mu rẹ."

Ojo ni wọn maa n ṣọ ki ere oko to ba ṣoriire le hu jade.
Ẹbẹ awọn araalu yii ko lopin tori wọn o ri ọna abayọ si ọpọ ohun to yẹ ki wọn fi raye gbe.
Ẹwẹ, nigba ti BBC kan si ẹka ijọba Kwara lori ọrọ omi, wọ́n fesi pe, o yẹ ki ilu naa tọ awọn wa, awọn o si wa nka ṣe toripe kii ṣe gbogbo ilu lawọn le mọ.


