Water Scarcity in Ogun Community: Àwa àtàwọn máàlù la jọ ń du mu omi yìí láti mu
"Bí omi yii ti a n mu ṣe ri latigba ti alaye ti daye ti a si n mu u niyii".
Ni ilu kan, Igbooro/Orobiyi ni agbegbe ijọba ibilẹ iha Ariwa Yewa, ipinlẹ Ogun ni omi idọti yii ti n gbayii gẹgẹ bi eyi to ṣi mọju ti wọn n bu mu, bu wẹ, bu dana jẹun.

Pẹlu bi ajọ isọkan agbaye UN ṣe n pariwo fun ipese omi to mọ gaara to, ilu yii ko ni orisun omi to dara fun mimu rara.
- Iléèwé gírámà Kwara mẹ́wàá tí ijọ́ba tipa lórí wíwọ Hijab kó tún ní wọlé padà lónìí
- Kò rí bákan lára ààrẹ o! Déédé ni abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 rí lára ààrẹ Buhari - Femi Adesina
- Kí nìdí tí gbajúgbajà òṣèré Sotayo Gaga ṣègbéyàwó bóńkẹ́lẹ́?
- 'Ọkọ mi, Professor Abiola Peller n kírun lọwọ ni, orí ìkírun Sujud lo wà tí àwọn tí wan fi ṣọ́ ọ pa'

Awọn ara ilu Igorọ ni omi abata ati ẹrọfọ ni awọn n ri pọn lati lo.
Janet Opeisa to jẹ ọkan lara awọn olugbe ilu Igborọ mu BBC Yoruba rin irinajo ti kii ṣe keremi lọ sinu ira ti wọn ti n pọn omi.

"A o tun ni ibi kankan mọ o, aa wa gbe e kalẹ, aa joko aa maa yọ ọ. Ki la fẹ ri ninu eleyii?".
O ni to ba ṣe pe awọn Fulani darandaran ti yọju si ilu wọn pẹlu awọn maalu wọn ni, omi yii kan naa lawọn n jọ n mu.
"Táa bá ní kí àwọn Fulani àti máàlù wọn má wẹ sínú omí yìí, wọn á ní orí wa ti dàrú".

Ẹwẹ, tori eyi, BBC Yoruba kan si ijọba ipinlẹ Ogun ti wọn si fesi pe awọn ni ileeṣẹ to n mojuto eyi ti wọn si ti gbẹ kọnga si aimoye ilu...
Kí wá ni àwọn ara ilu Igborọ ni Yewa fi ṣe ori ti mudunmudun yii ko tii kan wọn latigba ti alalye ti daye gẹ́gẹ́ bi wọ́n sọ.