Sotayo Gaga Sobola husband: Àwọn èèyàn fẹ́ mọ ọkọ gbaju

Sotayo Gaga

Oríṣun àwòrán, SotayoGaga/Instagram

O jọ gate ko jọ gate, gbajugbaja oṣerebinrin, Soyayo Sobola ti ọpọ eniyan mọ si Sotayo Gaga naa ti darapọ mọ awọn obinrin nile ọkọ.

Bonkẹlẹ lo ṣe e ṣa toripe gbogbo eto igbeyawo ọhun ko han si awọn ololufẹ rẹ rara ni gbangba.

Àkọlé fídíò, Wo ohun tí Professor Peller wí tó kó bá a gẹ́gẹ́ bí ìyàwó rẹ̀, Lady Peller ṣe tú u síta

Ninu awọn fọto ati fidio to fi sita lori ayelujara funrarẹ ni awọn akẹgbẹ rẹ ti n ki i ku oriire to fi mọ awọn ololufẹ rẹ gẹgẹ bi o ṣe ro dẹdẹ to kan dẹdẹ ninu aṣọ igbeyawo funfun balau to balẹ dẹdẹ.

Awọn ami taa ri lati mọ boya Sotayo ṣe igbeyawo

Sotayo Gaga

Sotayo Gaga kọ ọ sita si oju opo rẹ pe "bo tilẹ jẹ kii ṣe eni (ọjọ Satide) ni igbeyawo yii waye, mo kan yan lati fi sita loni ni, Mo dupẹ lọwọ gbogbo eniyan fun ọrọ ikini ati adura. Ọlọrun a bunkun yin".

O tun dupẹ lọwọ awọn ileeṣẹ to ṣe e loge ara, awọ, aṣọ ati irun to jẹ ara ọtọ fun igbeyawo rẹ.

Bakan naa ni ọjọ bii mẹta ṣaaju ọj to fi fọto sita, lara awọn esi lori fọto kan to fi sita to ti wọ iro ati buba ni ọkan lara awọn akẹgbẹ rẹ ti ki i ku imura iyawo amọ to tilẹ n ya awọn ololufẹ rẹ mii lẹnu pe imura iyawo kẹ.

Sotayo Gaga

Oríṣun àwòrán, SotayoGaga

Nigba ti a fi n ko iroyin yii jọ, atẹjade rẹ ti fa ọpọlọpọ esi mọra lati ọdọ awọn oṣere akẹgbẹ rẹ ti wọn n yẹ ẹ si atawọn ololufẹ rẹ gbogbo.

Lara awọn akẹgbẹ rẹ to ti ki i ku oriire ni ni Odunlade Adekola, Iyabo Ojo, Wumi Toriola, Kolawole Ajeyemi, Itele, Funke Akindele, Femi Adebayo, Bimbo Oshin, Bimpe Akintunde, Temitope Solaja.

Bẹẹ naa ni awọn to sun mọ ọ n tun fọto rẹ lo loju opo tiwọn naa lati ba a yọ ayọ igbeyawo.

Sotayo Gaga

Oríṣun àwòrán, SotayoGaga

Amoṣa lori ọrọ aridaju, iroyin kan n fihan pe awọn kan sibẹ lagbo oṣere n sọ pe ko ṣegbeyawo rara.

Ẹwẹ, iyawo funrarẹ naa ko kọ orukọ tabi fi fọto ọkọ rẹ si oju opo rẹ rara.