Fulani Herders invasion: Àwọn Fulani ń bérè fún ọjọ́ márùn ún síi

Fidio kan wa to n tan kalẹ pe lori ọrọ ki awọn Fulani maa ṣi kuro ni ilu kan lọ si omiran, wọn tun ti ri wọn ninu igbo ilu Ajowa nipinlẹ Ondo.
Atawọn ọdọ́ ilu atawọn to gbọ ede Hausa lo ti wa lori ọrọ yii ti wọn si ni awọn n fẹ ki Fulani ko ẹru wọn kuro nilu awọn.
Ọkan lara awọn to n gbe ilu yii to tun jẹ ọkan lara awọn ọdọ, Monday sọ fun BBC Yoruba pe lootọ ni iṣẹlẹ yii waye ti kii sii ṣe iroyin ọjọ to pẹ rara.
"Ọsẹ to kọja yii gan la gbọ pe awọn "Truck" meji ni awọn Bororo wọ de apa ibikan ni ilẹ Ajowa".
- Kí nìdí tí gbajúgbajà òṣèré Sotayo Gaga ṣègbéyàwó bóńkẹ́lẹ́?
- Èsì tí Daddy Freeze fọ̀ lórí owó N5m tí ilé ẹjọ́ ní kó san fún ọkọ obìnrin tó yàn l'álè rèé
- Israel Adesanya fojú winá ẹ̀ṣẹ́ lọ́wọ́ Jan Blachowicz, ó fìdí rẹmi
- Kò rí bákan lára ààrẹ o! Déédé ni abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 rí lára ààrẹ Buhari - Femi Adesina
O ni Ọgbẹni Ojo kan ni ilu Uro lo fun awọn Bororo naa ni ilẹ ti wọn si n san owo fun un bii onilẹ ti wọn wa lori rẹ.
Arakunrin naa ni awọn gbera gẹgẹ bi ọdọ ilu awọn si tọpasẹ wọn lọ sinu igbo naa ti wọ́n si ri i pe lootọ ni wọn wa nibẹ awọn si pe awọn to tun jẹ bi ẹgbọn fun wọn.
Monday ni ọrọ naa gan ti de ọdọ gomina bayii.
"Mo mọ wipe ilẹ merẹnti ni ilẹ naa ti ọgbẹni Ojo yẹn to ni ki wọ́n maa bọ to si n gba owo lọwọ wọn yoo ti ba wọn ni adehun iye owo ti wọn yoo maa san.
Awọn Fulani bẹbẹ fun ọjọ marun sii lati lo ni ilu Uro, Ajowa
Ọkan lara awọn ọdọ ilu naa sọ fun BBC Yoruba pe nigba to ya ti awọn kan laarin ilu ti yọju si awọn Fulani naa, atawọn ati onilẹ wọn gba pe wọn yoo kuro lori ilẹ naa ki wọn si kuro ni ilẹ Ajọwa.
"Ipenija ti wọn ni awọn ti wọn si ti lọ ba Kabiyesi Oluro bayii ni pe gbedeke ọjọ Ẹti ti wọn da awọn lati kuro, awọn ko ni le ba a pe ki wọn jọọ ki wọn tun fun awọn ni ọjọ marun sii.
Wọn sọ eyi nitori isuna amọ wọn sọ̀ fun Kabiyesi pe ki o fun awọn ni ọjọ marun sii ki awọn lee sare kiri ko owo jọ ti wọn lee lo.
Lara awọn to yọju sinu igbo naa sọ pe lootọ ni fidio to tan kalẹ amọ awẹ́ kan fẹ ka a silẹ ni ọjọ ti wọn wọ ilu yẹn n lọ ni oru ni wọn de".
O ni awọn ti lọ tawọn ti Ọgbẹni Ojo ti wọn sọ pe o fun awọn aaye lati maa gbe ti wọn si sọ o loju rẹ naa pe awọn ti gba lati lọ.














