Akomolede Ondo: Àwọn Olùkọ́ Yorùbá ní ìlú Ondo fọkọyọ lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC Yorùbá

akomolede

Awọn olukọ ede Yoruba ni ilu Ondo ni ipinlẹ Ondo ni guusu Naijiria ni wọn kọ awọn koko ti a n gbeyẹwo lasiko yii.

Awọn olukọ to dantọ yii kọ wa ni awọn ẹkọ kọọkan ni eyi ti o gbe aṣa, ede ati igabgbọ Yoruba sita sii.

Àkọlé fídíò, Mother tongue day 2021, Akomolede, YSAN: A ti parí iṣẹ́ lórí èdè ìperí Meta-Language Yorùb

Eto Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba jẹ eto ti a ti n kọni lẹkọ nipa Yoruba eyi ti BBC n ṣe pẹlu apapọ ẹgbẹ Akọmọlede ati Aṣa

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa: Mọ̀ si nípa àwọn ọ̀nà tí Yorùbá ń gbà ran ara wọn lọ́wọ́

Iwi Egungun jẹ koko ti olukọ Olalekan Ojelade to wa lati ileẹkọ Orisunbare Number Community High School ni Bankẹmọ ni Ondo lo kọ ọ.

Àkọlé fídíò, Eégun àti orò, bí wọ́n ṣe jọ bí Ẹ̀ṣà Egúngún nílẹ̀ Yorùba rèé

Asiko ati Iba Iṣẹlẹ ni koko ti Alagba Okunlọla J.A kọ wa.

Lati ileẹkọ Community High School ni Asewele-korede ni agbegbe Odigbo-Ọrẹ ni ẹkun Ondo ni olukọ to kọ koko yii.

Olukọ yii mẹnuba awọn ọrọ ti a n sọ nipa iṣẹlẹ ati asiko ti iṣẹlẹ n ṣẹlẹ nigba naa.

Àkọlé fídíò, Kí ni "Present tense" lédè Yorùbá?

Iwe litireṣọ apilẹkọ Aja lo lẹru láti ọwọ ogbontarigi onkọwe ni, Oladejọ Okediji.

Arabinrin Kikelomo Ogunboye lo kọ wa nipa ẹda itan, ẹkọ inu iwe naa, awon ibudo itan ati itan inu iwe naa ni ṣoki.

akomolede

Ileẹkọ St Monica Girl's Grammar School, ni ipinlẹ Ondo.

Olukọ wa fi ara balẹ yannana ohun gbogbo to ṣẹlẹ nibẹ ati ipa ti Tafa, Lapade, ati awọn ẹda itan miran ko ninu ifọrọyaworan to nii ṣe pẹlu ohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa lori BBC: Olùkọ́ Kikelomo Ogunboye tan ìmalẹ̀ sí ìwà olè ọ̀gá ọlọ́pàá

Aranmọ Fawẹẹli ni koko girama ti a gbe yẹwo.

Alagba Oyewọle Isaac, lati ileẹkọ Awaye Comprehensive Grammar School, Ilẹ̀ Oluji ni ipinlẹ Ondo.

Olukọ wa mẹnuba awọn iro agbaranmọ ati iro afaranmọ,.

Bakan naa lo sọ nipa awọn ọna ijẹyọpọ fawẹẹli ati bi aranmọ ṣe n waye ninu gbolohun ede Yoruba.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa: Mọ̀ síi nípa ìró afárànma àti agbárànmọ́ fáwẹ́ẹ̀lì Yorùbá

Iwa Omoluwabi ni a gbe yẹwo ni kilaasi yii.

Arabinrin Adenikẹ Okun lo kọ wa ni koko naa lati ileẹkọ St Andrews Anglican Grammar School ni ipinlẹ Ondo.

Olukọ to yaranti yii sọrọ nipa awọn iwa ọmọluabi bii otitọ inu, ifẹ, ibọwọfagba, itẹriba, ifọwọsopọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O mẹnuba awọn iwa ti kii ṣe ti ọmọluwabi bii irọ pipa, ole jija, rikiṣi ṣiṣe, imọtara ẹni nikan, ọtẹ ṣiṣẹ atawọn nkan imii.

Olukọ wa sọ awọn anfani nini iwa ọmọluwabi pelu iṣẹ aṣetilewa fun awa akẹkọọ.

Àkọlé fídíò, Ṣé ẹ mọ̀ pé àṣà nílẹ̀ Yorùbá ni ìwà ọmọlúàbí?

Arabinrin Adeyemi Taiwo lati ileẹkọ C.A.C. Grammar school Ọ̀kà, Ondo West.

Gbolohun ede Yoruba ni koko ti olukọ wa gbe yẹwo

Awọn isọri ọrọ to n wa ninu gbolohun ede yoruba ni a gbe yẹwo ati ọna ti wọn fi n jẹyọ.

Àkọlé fídíò, Akomolede BBC: Onírurú gbólóhùn léde Yorùbá àti irúfẹ́ gbolóhùn tó wà nínú èdè Yorùbá

Awọn ounjẹ ilẹ̀ Yoruba ni a gbe yẹwo lonii lori eto Akọmọlede ati Aṣa lori BBC Yoruba.

Arabinrin Stella Adedeji ni olukọ wa lati ileẹkọ C. A. C. High School ni ilẹ Oluji ni ipinlẹ Ondo ni guusu Naijiria.

Olukọ wa mẹnuba awọn oriṣii ounjẹ to wọpọ ni awọn agbegbe kọọkan ati bi wọn ṣe n se wọn.

Àkọlé fídíò, Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC Yorùbá: Kọ̀ síi nípa iṣẹ́ tí oúnjẹ ń ṣe lára níbí

Iwe itan Akojọpọ Alọ Ijapa lati ọwọ Ọjọgbọn Adeboye Babalola.

Alagba Oyelọwọ Lawrence Olufemi lati ile ékọ C.A.C. grammar school, Ọ̀kà ni ipinlẹ Ondo ni olukọ wa lori eto Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba toni.

Olukọ wa yanana idi ti Yoruba se n lo ijapa gẹgẹ bii olu ẹda itan alọ apagbe wọn.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa Ondo: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelo

O mẹnuba awọn ọgbọn ẹwẹ ti ijapa ni, awọn iwa to n hu lati fi kọ ọmọ araye lọgbọn.

E to yii n waye pẹlu ajọṣepọ BBC Yoruba, ẹgbẹ Onimọ Yoruba YSAN ati apapọ ẹgbẹ Akomolede ni Naijiria

akomolede