Buhari, Osinbajo ti gba abẹ́rẹ́ ajẹsára Covid-19 Oxford-AstraZeneca

Aarẹ Buhari gba abẹrẹ

Oríṣun àwòrán, Fem i Adesina/Facebook

Ni idahun si oniruuru ibeere ti awọn oniroyin n fi ṣọwọ si awọn oṣiṣẹ aarẹ Muhammadu Buhari lẹyin to gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19, agbẹnusọ aarẹ Buhari, femi Adesina ti fi ọrọ kan sita eyi ti oluranlọwọ pataki fun aarẹ Garba Shehu fọwọ si sita.

"Mo fẹ fi da gobogbo araalu loju ati lati mu ibẹru ati igbagbọ odi kuro lọkan awọn eeyan nipa abo abẹrẹ ajẹsara ti wọn fun aarẹ Muhammadu Buhari ati igbakeji rẹ".

Àkọlé fídíò, Wo ohun tí Professor Peller wí tó kó bá a gẹ́gẹ́ bí ìyàwó rẹ̀, Lady Peller ṣe tú u síta

O ni lẹyin ti aarẹ gba tirẹ si apa tan, ara wa bo ṣe wa tẹlẹ to si tẹsiwaju ninu iṣẹ rẹ. O ni bi ipalara kankan ba pada wa, awọn ko ni fi ohunkohun bo "ṣugbọn titi di asiko yii, ko si ipalara kankan yala o lagbara ni abi o kere lori aarẹ. O n ṣe ohun to yẹ ko ṣe".

"A lero pe eyi yoo ṣeranwọ lati fi ọrọ to nipọn ranṣẹ si awọn eeyan paapaa julọ awọn to fi aifẹ gba tabi ọrọ boya o n ṣiṣẹ ati abo abẹrẹ ajẹsara naa ṣere".

Buhari ati Osinbajo gba abẹrẹ ajẹsara

Oríṣun àwòrán, FEMI ADESINA/FACEBOOK

Mo ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19, ẹ̀yìn nàá ẹ lọ gbà á - Ààrẹ Buhari

Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari ati igbakeji rẹ, Yemi Osinbajo ti gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19.

Eyi waye lẹyin ọjọ kan ti wọn bẹrẹ si ni fun awọn oṣiṣẹ eto ilera ni Naijiria ni abẹrẹ naa.

Ile ijọba Aso Rock nilu Abuja ni aarẹ ati igbakeji rẹ ti gba ti wọn, wọn si ṣafihan eto naa lori amohunmaworan.

Aarẹ Buhari sọ pe bi oun ṣe gba abala akọkọ abẹrẹ naa, oun rọ awọn ọmọ Naijiria to ni ẹtọ lati gba, ki awọn naa ṣe bẹ ẹ.

Aarẹ Buhari mu kaadi abẹrẹ ajẹsara dani

Oríṣun àwòrán, Femi adesina/facebook

Ọga agba ajọ eto ilera alabọde ni Naijiria, Dokita Faisal Shuaib sọ pe ireti wa pe bi aarẹ ṣe gba abẹrẹ ajẹsara naa yoo ṣe iwuri fun awọn araalu lati gba fun idaabo bo lọwọ Covid-19.

Ọjọ Aje ni awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ Aarẹ Buhari yoo bẹrẹ si ni i gba, gẹgẹ bi ikede ti Dokita Shuaibu fi sita.

Àkọlé fídíò, Oba Sunday Oyediran ṣàlàyé kíkún nípa ìṣẹ̀ṣe, ìgbàgbọ́ àti ẹ̀sìn tí kò dí ará wọn lọ́wọ́

Awọn oṣiṣẹ eto ilera ti di awọn eeyan akọkọ ti yoo gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ti Oxford-AstraZeneca ṣe ni Naijiria.

Adari ileeṣẹ to n ri si eto ilera alabọde, Faisal Shuaib lo ṣide eto naa nibi to ti fun dọkita akọkọ labẹrẹ ọhun ni Naijiria, iyẹn Cyprian Nyong.

Shuaib sọ pe awọn oṣiṣẹ eto ilera to n ṣiṣẹ julọ lasiko ti ajakalẹ arun naa milẹ titi lo kọkọ nilo abẹrẹ ọhun lati dabo bo wọn.

Aadọjọ awọn oṣiṣẹ eto ilera miran yoo gba ọhun laipẹ lẹyin ti ajọ to n ṣakoso ounjẹ ati oogun lilo ti buwọlu.

Eyii to n tumọ si pe kii ṣe Aarẹ Muhammadu Buhari ni yoo kọkọ gba abẹrẹ naa ni Naijiria gẹgẹ bo ṣe ri lawọn orilẹ-ede miran.

Vaccination

Oríṣun àwòrán, Reuters

Aarẹ Ghana, Nana Akufo-Addo lo kọkọ gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 lẹyin ọjọ kan to balẹ si orilẹ-ede ọhun.

Lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹta, ọdun yii ni Aarẹ Buhari yoo gba abẹrẹ tirẹ, toun ti igbakeji rẹ, Yemi Osinbajo.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho latest: Sunday Igboho kò gba 'Award'ti a fún un ní Ogo Yorùbá nítorí inú rẹ̀

Bi eto abẹrẹ gbigba ọhun yoo ṣe lọ niyii; lẹyin ti awọn oṣiṣẹ eto ilera, Aarẹ ati igbakeji rẹ ba ti gba abẹrẹ tiwọn tan ni yoo kan awọn gomina.

Ni kete ti awọn gomina ọhun ba ti gba abẹrẹ ọhun tan, lọjọ kejila, oṣu Kẹta, lati ṣafihan fun awọn awọn eeyan ipinlẹ wọn pe abẹrẹ naa ko mu ewu lọwọ ni yoo kan awọn ara ilu.

Gbogbo awọn ipinlẹ ti ko ba kun oju oṣuwọn gbigba abẹrẹ naa, bii ẹrọ to le mu abẹrẹ ọhun tutu ko ni lanfani lati gba a.

Ẹwẹ, gbogbo awọn ti yoo gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ni Naijiria gbọdọ fi orukọ lẹ loju opo ti ijọba ti fi lọlẹ fun eto ọhun.

Àkọlé fídíò, Bone setting: Adimula Kehinde Akinfenwa ṣàlàyé nípa irúfẹ́ ẹranko tí wọ́n fi ń to eegun èy