South-Africa Crocodiles: A ti rí Ọọ̀nì ''crocodile'' 27 nínú àwọn tó sálọ, ẹ̀yin ará ìlú, ẹ ṣọ́ra

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba orilẹede South-Africa ti kede wi pe awọn ṣi n wa awọn ọọni to sakuro ni ibi ti wọn ti n ṣin wọn ni agbegbe Western Cape Province, lorilẹede naa.
Awọn alaṣẹ ni awọn ti ri mẹtadinlọgbọn ninu awọn ooni naa, amọ awọn ko mọ iye awọn to ku ti wọn ṣi n wa.
Awọn ooni naa ni wọn sa kuro ni agbegbe gba ogiri kan to ya lulẹ ni ibi ti wọn ti n sin wọn ni Bonnievale, ti wọn si wọ inu omi Breede River.
- Bone setting: Adimula Kehinde Akinfenwa ṣàlàyé nípa irúfẹ́ ẹranko tí wọ́n fi ń to eegun èya ara èèyàn
- Wo ohun mẹ́fà tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìbọn AK-47
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn tó ń ṣe ayédèrú abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19
- Buhari ni káwọn agbófinró ó yìnbọn fáwọn tó ń gbé ìbọn AK-47, àwọn ọmọ Nàìjíríà n pariwo "lórí irọ́"
Ijọba si ti kilọ fun awọn araalu lati ṣọra fun awọn ọọni ti wọn ba ri ni agbegbe wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
''Awọn ọọni yii lewu, ẹranko igbo ni wọn, bi o tilẹ jẹpe ojukan ni wọn ti sin wọn.
''Awọn eniyan gbọdọ ṣọra fun agbegbe naa, titi ti wọn yoo fi ri awọn to ku gbe''.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọọru, Ọjọ Kẹta, Oṣu Kẹta ni awọn ọọni naa ti wọn gun to iwọn mita kan abọ 1.5m (4ft 11in) sa kuro nibi ti wn ko wọn si.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa ti gbe ikọ kan kalẹ lati sawari awọn ọọni naa, ki wọn si gbe wọn si inu awọn ni eti omi CapeNature naa.
- Nǹkan dé, Igboho ní káwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ Yorùbá lọ múra ògùn jọ nítorí ohun tó ń bọ̀ lọ́nà
- Wo ibi tí o ti lè fi orúkọ síìmù rẹ sílẹ̀ tàbí gba nọ́mbà tuntun tí síìmù rẹ bá sọnù
- Àwọn ará abúlé kan ṣàwàrì àlùmọ́ọ́nì gòólù ní wọ́n bá kígbe síta ní Ọlọ̀pàá bá yi wọn ká!
- Baba tó dàbí MC Oluomo láyé yìí kò sí, ẹni tó bá níi, ó ní ohun gbogbo- Ọmọ MC Oluọmọ
- Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Sadiq Daba 'Inspector Waziri' nínú sinimá October 1 tó jáde láyé rèé












