Congo gold mountain: Àwọn ará abúlé kan ṣàwàrì àlùmọ́ọ́nì gòólù ní wọ́n bá kígbe síta ní Ọlọ̀pàá bá yi wọn ká!

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọlọpọ nkan ni awọn eeyan ti n sọ lori ayelujara nipa iṣẹlẹ yii to waye ni orilẹ-ede Congo.
Ni DR Congo ni awọn ara abule kan ti ṣẹgi ọla laimọ rara pe ọla naa ti n ba awọn gbe lati ọdun to ti pe wa.
- Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Sadiq Daba 'Inspector Waziri' nínú sinimá October 1 tó jáde láyé rèé
- Baba tó dàbí MC Oluomo láyé yìí kò sí, ẹni tó bá níi, ó ní ohun gbogbo- Ọmọ MC Oluọmọ
- Ìjà ti parí, a ti gbà láti má a gbé ounjẹ wá sí ilẹ̀ Yoruba padà'- Hausa-Fulani Ọlọ́jà
- "Sọ́jà fi ìbọn gé mi lọ́wọ́ kó lè fipá bámi lòpọ̀"
- Wọ́n tún yìnbọn níbi àpèjẹ 'Ẹ káàbọ̀' tí wọ́n ṣe fáwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Zamfara lẹ́yìn àṣẹ Buhari
Ki lo ṣẹlẹ gangan ni Birava ni DR Congo?
Saaju ni awọn eniyan abule Birava to jẹ iwọn kilomita marundinlogoji si ariwa ẹkun Bukavu ni aarin gbungbun ilu South-Kivu ni ẹkun kan naa.
Byode Malenga to jẹ akọroyin BBC ni DR Congo ṣalaye pe labule ni wọn ti deedee rii pe goolu wa ninu iyẹpe ori oke kan nibẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Leyin ti awọn eeyan abule yii ri goolu yii, ni wọn bẹrẹ si ni fọọ ninu omi to si di goolu to dara.
Ni kete ti wọn rii ni ọpọ ero rọ lọ si ori oke naa ti wọn si bẹrẹ si ni gbọn iyẹpẹ ori oke naa ti onikaluku si lọ n fọ goolu jade nibẹ ti wọn n di ọlọla.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ko pẹ lẹyin naa ni awọn kan fi si ori ayelujara ohun to n ṣẹlẹ ti koowa si di ero ibẹ ti wọn si n pin in kaakiri lori ayelujara.
Kini Ijọba DR Congo ti wa ṣe bayii?
Ni kete ti iroyin naa tẹ ijọba DR Congo lọwọ ni wọn ti ran awọn agbofinro kọja lọ sibẹ pe ki wọn lo mojuto ori oke naa ti goolu wa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Koda, iroyin ni ijọba ti da awọn agbofinro sita lati lọ maa gba awọn goolu ti awọn eeyan mii ti ko ni abule naa pada.
Orilẹ-ede DR Congo jẹ ọkan lara awọn orilẹ-ede ilẹ Adulawọ to ni awọn ohun alumọọni pupọ bii goolu, ati awọn nkan miran.

Oríṣun àwòrán, @Ahmad
Akoroyin BBC, Malenga ṣalaye pe kii ṣe awọn awakusa nikan loju wọn hande ninu fidio naa to jade lori ayelujara.
Malenga ni lati opin ọsẹ to kọja ni iṣẹlẹ naa ti bẹrẹ, ki fọnran fidio naa to jade lẹyin naa.
Wọn ni goolu to to ida 60 ninu 100 si ida 90 ninu 100.
- Wọ́n tún yìnbọn níbi àpèjẹ 'Ẹ káàbọ̀' tí wọ́n ṣe fáwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Zamfara lẹ́yìn àṣẹ Buhari
- Wo ibi tí o ti lè fi orúkọ síìmù rẹ sílẹ̀ tàbí gba nọ́mbà tuntun tí síìmù rẹ bá sọnù
- Àwọn tó jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin gbé ní Zamfara fẹ́ yẹ̀yẹ́ Ìjọba Buhari ni- Hadi Sirika
- Ewú ńbẹ! tí ìjọba ìpínlẹ̀ bá sàkóso gbèndéke owó oṣù òṣìṣẹ́,wọ́n ò ní san N30,000, N10,000 ní wọ́n má á san -NLC