Zamfara kidnapping, Shooting: Àwọn Agbébọn ti dáná sún agbègbè Maru nípinlẹ̀ Zamfara, wọ́n tún jí èèyàn tó lé lọ́gọ́ta gbé lọ

Zamfara

Oríṣun àwòrán, @Nigeria Army

Awọn olugbe agbegbe Ruwan Tofa nijọba ibilẹ Maru ni ipinlẹ Zamfara ti ko sọwọ awọn agbebọn bayii.

Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe niṣe ni awọn agbebọn kan deedee yabo abule yiii ti wọn si sọna si inu rẹ.

Bayii, wọn ni ilaji abule naa ti jona tan pẹlu ọpọlọpọ dukia lo ti ṣofo danu.

Eyi n waye lataari iṣoro ijinigbe to n pọ sii nibẹ ni eyi ti o mu ki aarẹ Buhari kede "No-Fly Zone" nibẹ lẹyin ti wọn ji awọn akẹkọọbinrin 279 gbe.Wo ohun tí Ńo-Fly Zone' túmọ̀ sí,

Awọn olugbe agbegbe Ruwan Tofa ti sa asala kuro ninu abule naa ni Zamfara bayii.

Wọn ṣalaye fun awọn akọroyin pe lati ọdun to kọja ni awọn ti n la iṣoro eto aabo kọja ninu eyi ti wọn ti jo awọn ọkọ ayọkẹlẹ wọn, ile itaja wọn, ile ati awọn dukia to pọ.

Wọn ni o le ni eeyna ọgọta ti wọn ti ko salọ kuro ni abule naa bayii.

Àkọlé fídíò, Francis Olusola Alao: Wọ́n ti ti ọ̀rọ̀ òṣèlú bọ ọ̀rs Sunday Igboho, ṣùgbọ́n..- Oba Olugbọn

Awọn ọmọ wẹwẹ, awọn Obinrin lo pọ ti wọn le ni ọgọta ti wọn ti dawati bayii.

Okunrin kan, Maigari ni iyawo oun merin ati awọn ọmọ lo ti dawati bayii.

Enikan naa tun sun pe eeyan mẹẹdogun lo ti sọnu ninu ile ti oun.

Wọn ni ẹẹmeji ni wọn pe awọn agbofinro ṣugbọn nigba ti a ko ri ẹṣọ alaabo kankan la ṣe sa asala fun ẹmi wa.

Nigba ti BBC kan si ileṣẹ ọlọpaa ni Zamfara ṣugbọn a ko ri nkankan di mu, a ko dẹ ri ẹnikankan ba wa yanayana ọrọ naa.

Àkọlé fídíò, Fulani-Yoruba Crisis: Oba Soun ló fí mi jẹ ọba Sabo ni Ogbomọṣọ- Alh Haruna Bala Abdulsala

Saaju ni awọn agbebọn tunti ji awọn ọmọ kan gbe ni Runka nipinlẹ Katsina,

Ara ilu Runka ni pe wọn ji akẹkọọ mẹta gbe ni ọjọ Iṣẹgun to kọja.

Wọn ni wọn ji awọn akẹkọọ yii gbe nigba ti wọn n bọ lati ile ẹkọ lo sile Obi wọn.

Zamfara

Oríṣun àwòrán, @Zamfara Govt

Wọ́n tún yìnbọn níbi àpèjẹ 'Ẹ káàbọ̀' tí wọ́n ṣe fáwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Zamfara lẹ́yìn àṣẹ Buhari

Wọ́n tún yìnbọn níbi àpèjẹ 'Ẹ káàbọ̀' tí wọ́n ṣe fáwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Zamfara lẹ́yìn àṣẹ Buhari

Lẹyin ti aarẹ Muhammadu Buhari kede pe ipinlẹ Zamfara ti di " No-Fly Zone" Wo ohun tí Ńo-Fly Zone' túmọ̀ sí, eruku tun sọ lala nibẹ.

Niṣẹ ni nkan bẹyin yọ nibi apejẹ ẹ kaabọ pada sile ti wọn ṣeto fawon akẹkọọbinrin ile ẹkọ GSS Jangebe.

Iroyin ti a gbọ nipe ija bẹ silẹ nigab ti awọn alaṣẹ ipinlẹ Zamfara lọ ko awọn ọmọ naa fun Obi wọn nibi apejẹ naa.

Awọn ara ilu Jangebe kan sọ fun BBC pe wahala bẹ silẹ nigba ti awọn ara abule bẹrẹ si ni sọ awọn alaṣẹ ni okuta lasiko ti wọn de lati da awọn akẹkọọbinrin naa pada fun awọn Obi wọn.

Eni ti ọrọ naa ṣoju ẹ sọ fun BBC pe o kere tan eniyan mẹta ni awọn ọmọ ogun ilẹ to wa nibẹ yinbọn fun.

O ni bi awọn ara ilu ṣe n sọ awọn alaṣẹ to tẹlẹ awon ọmọ naa wa loko ni awọn ṣọja ṣina bolẹ nibẹ.

Àkọlé fídíò, Olusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun

A ko tii le sọ boya ẹnikẹni ku ninu iṣẹlẹ naa tabi bẹẹkọ titi di asiko yii.

Lọjọ Eti to kọja ni wọn ji awọn akẹkọọbinrin yii gbe ti wọn si tu wọn silẹ lẹyin ti ijọba ni wọn gbiyanju pupọ.

Àkọlé fídíò, Francis Olusola Alao: Wọ́n ti ti ọ̀rọ̀ òṣèlú bọ ọ̀rs Sunday Igboho, ṣùgbọ́n..- Oba Olugbọn

Awọn akẹkọọbinrin 279 yii ti wa lọdọ ijọba ipinlẹ Zamfara nile ijọba ni Gusau to jẹ olu ilu Zamfara lati ọjọ Isẹgun ti ijọba kede pe wọn ti ri wọn gba pada.

Nile ijọba ni wọn ni wọn ti n gba itọju ki wọn to fẹ da wọn pada sọdọ Obi wọn to fi di iṣu ata yanyan.

Zamfara

Oríṣun àwòrán, Others

Ni kéte lẹyin ti ijọba ri awọn akẹkọọbinrin yii gab pada ni Aarẹ Buhari kede pe ki ọkọ ofurufu kanakan ma rin mọ ni Zamfara.

Àkọlé fídíò, #EndSars Ogbomoso: Èmí kò ní kí wọ́n pa ọlọ́pàá tó pa Isisaka, ṣùgbọ́n...- Ramota, Iya Isi

Garba Shehu ṣalaye idi ti ijọba Buhari fi paṣẹ yii fun BBC pe o nii ṣe pẹlu awọn oniṣẹ ibi to n fi ọkọ ofuirufu aladani ji goolu ijọba wà lọ si Dubai.Wo ohun tí Ńo-Fly Zone' túmọ̀ sí

Koda, O ni eto aabo ẹkun ariwa yii ti gba amojuto ati awọn igbesẹ aṣẹ lati le daabo bo awọn ara ilu ibẹ.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Aṣa: Olùkọ́ Olajide láti Ẹdẹ ló ṣàlàyé nípa Awẹ́ Gbólóhùn fún wa ní kíkún