Fulani-Yoruba Crisis: Àwọn oníṣòwò Hausa ti ń kó ọjà wọlé padà- Aminu Alaba Rago

Food

Oríṣun àwòrán, others

BBC ti fidiẹ mulẹ pe awọn ọja ounjẹ ti pada n wọle bayii lati ariwa Naijiria wa si Iwọ oorun guusu ati ila oorun guusu.

Saaju ni awọn Ẹgbẹ Amalgamated Union of Foodstuff and Cattle Dealers of Nigeria (AUFCDN) ti kọkọ gunle iyanṣẹlodi Ọlọrun má jẹ́ kí a jẹ́ gbèsè lókù báyìí tí a kò kó ọjá lọ sílẹ̀ Yorùbá mọ́- Hausa Oníṣòwò

Iyanṣẹlodi yii mu nkan bajẹ lori igba ati ninu ọkọ awọn oniṣowo Hausa ni eyi to jẹ ki awọn eeyan Yoruba ma ra ounjẹ bii Tomati, alubosa, Ewa, Agbo ati bẹẹ bẹẹ lọ lowo gọbọi.

Lẹyin ipade loriṣiiriṣii ni wón wọgile iyanṣẹlodii naa lẹyin ti wọn fẹnuko lori awọn nkan kọọkan.

Alaga ẹgbẹ Amalgamated Union of Foodstuff and Cattle Dealers of Nigeria (AUFCDN), ẹka Alaba Rago, Alhaji Aminu lo fidiẹ mulẹ fun BBC pe ọja ti n wọle si ipinlẹ Eko atawọn ipinlẹ to kù.

O ni gbogbo awọn ọkọ akẹru ati tirela ti wón da duro tẹlẹ ni oju ọna ni ipinlẹ Kwara ati Niger ni awọn ti ri ti wọn ti n kọja wọle bayii.

Gbogbo ọja to ha si opopona tẹlẹ ti wọ awọn ipinlẹ ile Igbo ati ti ilẹ Yoruba.

Saaju ni awọn oniṣowo Hausa ti a ba sọrọ ti fi aidunnu han lori awọn nkan ti wọn padanu tẹlẹ.

Wọn ni awọn nkan ti awọn naa padanu ka wọn lara ṣugbọn aabo ẹmi ati dukia koowa lo jẹ gbogbo eeyan logun

Ẹlẹran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìjà ti parí, a ti gbà láti má a gbé ounjẹ wá sí ilẹ̀ Yoruba padà'- Hausa-Fulani Ọlọ́jà

Egbe awọn agbẹ olounjẹ lati Ariwa orilẹ-ede Naijiria pẹlu awọn Fulani darandaran (AUFCDN) ti gbegile iyanṣẹlodi ti wọn gunle.

Àkọlé fídíò, Fulani-Yoruba Crisis: Oba Soun ló fí mi jẹ ọba Sabo ni Ogbomọṣọ- Alh Haruna Bala Abdulsala

Ẹgbẹ Amalgamated Union of Foodstuff and Cattle Dealers of Nigeria (AUFCDN) naa ni awọn yoo bẹrẹ si ni gbe ounjẹ pada wa si Iwọ oorun orilẹ-ede Naijiria lasiko ipade pẹlu ijọba apapọ ti Gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello ṣe aṣoju fun ni ilu Abuja.

Ninu ọrọ tirẹ, gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello bẹ ẹgbẹ naa ki wọn fi opin si iyanṣẹlodi wọn, ti awọn yoo si ri daju pe gbogbo nkan ti wọn bere fun ni ijọba a fi fun wọn.

Gomina Bello ni gbogbo eniyan ni iyanṣẹlodi naa ta ba nitori awọn ọmọ Naijiria n la ọpọlọpọ idojukọ kọja nitori nkan to le, nitori naa ki wọn ma tun dakun iṣoro naa.

Àkọlé fídíò, #EndSars Ogbomoso: Èmí kò ní kí wọ́n pa ọlọ́pàá tó pa Isisaka, ṣùgbọ́n...- Ramota, Iya Isi

Aarẹ ẹgbẹ AUFCDN, Muhammed Tahir ni awọn gbe igbeṣẹ naa nitori ijọba gba lati san iye owo to le ni biliọnu mẹrin naira fun awọn fun gbogbo awọn nkan ti wọn padanu lasiko ija laarin awọn ẹya ni Naijiria.

Ipade pelu awon oloja

Tahir ni ijọba ṣeleri lati ri pe aabo to daju wa fun wọn loju ọna ti wọn ba n gbe ounjẹ bọ lati Ariwa ati opin si bi wọn ṣe n gba owo gọbọi ni ọwọ wọn ni oju ọna.

''Inu wa dun nitori gbogbo nkan ti a bere fun ni ijọba gba lati ṣe fun wa.''

Àkọlé fídíò, Olusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun

Tahir ni: ''Nitori ijọba ti Gomina Bello ṣoju fun bẹ wa wi pe awọn yoo ṣe ohun to tọ, ni awọn ṣe gbegile iyanṣẹlodi ọhun''

''Ijọba si ṣeleri lati pese aabo to tọ fun awọn ọlọja lati ariwa lati le ṣe iṣẹ wọn ni ọna to tọ''

Atarodo ati tomato

Bakan naa ni Minisita tẹlẹri fun ọrọ irinna ofurufu, Femi Fani Kayode ni Sunday Igboho ti fi da oun loju wi pe awọn Hausa-Fulani ko ni dojukọ ija ẹlẹyamẹya mọ.

Amọ, o kesi ijọba apapọ lati pese aabo to tọ fun awọn agbẹ naa ni ilẹ Yoruba nitori awọn Fulani darandaran to n pa awọn eniyan ninu igbo ijọba.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Aṣa: Olùkọ́ Olajide láti Ẹdẹ ló ṣàlàyé nípa Awẹ́ Gbólóhùn fún wa ní kíkún