Chimamanda Adichie: Bábá, ìyá Chimaamanda Adichie jáde láyé láàrín ọdún kan, kíló ṣẹlẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Google
Chimamanda Ngozi Adichie n ṣe daro awọn obi rẹ ti wn jade laye laarin ọdun kan.
Oṣu Kẹfa, ọdun 2020 ni baba rẹ, James Adichie jade laye lẹni ọdun mẹtadinladọrun ni ileewosan to ti n gba itọju lẹyin to ṣe aisan.
Bakan naa ni iya rẹ, ẹni ọdun mẹjidinlọgọrin naa fi aye silẹ lairotẹlẹ ni Ọjọ Kini, Oṣu Kẹta, ọdun 2021, lẹyin oṣu mẹsan ti ọkọ rẹ fi ayẹ silẹ.

Oríṣun àwòrán, Instagram/ChimamandaAdichie
Awọn ẹbi naa n ṣedaro iya ọmọ naa ati ọkọ rẹ to fi aye silẹ.
Awọn ọmọ Adichie to gbẹyin baba ati iya wọn ni Ijeoma, Uchenna, Chuks, Okechukwu, Chimamanda ati Kenechukwu pẹlu ọpọlọpọ ọmọ-ọmọ.
Amọ awọn ẹbi ko i tii sọ igba ti wọn yoo sin iya ọmọ to papoda naa.

Chimamanda Adichie jẹ ọkan lara awọn onkowe gboogi lati ilẹ Afrika to si jẹ ẹya Igbo, lorilẹede Naijiria.
Ajafẹtọ ọmọbinrin ni Adichie, to si ti gba ami ẹyẹ lọpọlọpọ fun iṣẹ ribiribi ti iwe rẹ n ṣe ni awujọ.
Ọmọ ipinlẹ Anambra ni,amọ ti wọn bi si ilu Enugu.
Baba Adichie lo gbe ile ogbajugbaja onkọwe, Chinua Achebe pẹlu awọn ọmọ rẹ mẹfa.
Awọn eniyan tilẹ sọ wi pe o ṣeeṣẹ ki ifẹ Chimamanda fun iwe ati iṣẹ rẹ gẹgẹ bi onkọwe niiṣe pẹlu ile Achebe ti wọn gbe naa.
- Àwọn ajínigbé fìyà jẹ́ wa lọ́nà igbò tí wọ́n kó wa lọ- Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin GSS Zamfara
- Ẹ wo èrò àwọn ènìyàn lórí bí Gòmìná Akeredolu ṣe fòfin de NURTW, RTEAN nípínlẹ̀ Ondo
- Iléeṣẹ́ ọmọ ogun ti fi akọ̀ròyìn BBC kan sí àtìmọ́lẹ́
- Owó Taxi ní ìpínlẹ̀ Ondo tí padà sí N50 látí N100 nítorí kò sí gbígba ''tíkẹ́ẹ̀tì'' NURTW mọ́
- Ọ̀jọ̀gbọ́n Ijeoma ní òun kìí ṣe ọmọ Nàìjíríà mọ́, South Africa tó yàn dípò bá tún lé e jáde














