Zamfara kidnapping: A ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ètò aà[bò míràn tó máa fi ará ìlú lọ́kàn balẹ̀- Hadi Sirika

Oríṣun àwòrán, @Sirika
Minista fun ọrọ ofurufu ni Naijiria, Hadi Sirika ti bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu iwa awọn agbebọn ni Naijiria.
O ni bi wọn ṣe ji awọn akẹkọọbinrin ti Jangebe yii gbe ni wọn kan fẹ fi tabuku aarẹ Buhari ati iṣẹjọba rẹ ni.
Ijọba apapọ ni Naijiria mẹnuba awọn igbesẹ akọtun lati mojuto ọrọ eto aabo ni Naijiria.
Ijọba ni oun ṣetan lati tubọ daabo bo awọn ọmọde ni pato.
Awọn igbese naa ni i ṣe pẹlu ajọsepọ pẹlu awon illeṣẹ ijọba, awọn ara ilu nibi ti iwa ibi yii pọ si, awọn akọṣẹmọṣẹ ninu eto aabo.
- Ewú ńbẹ! tí ìjọba ìpínlẹ̀ bá sàkóso gbèndéke owó oṣù òṣìṣẹ́,wọ́n ò ní san N30,000, N10,000 ní wọ́n má á san -NLC
- Àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tó dá mi lọ́nà lọ́jọ́ Ẹtì fẹ́ pa mí ni -Sunday Igboho
- Nǹkan dé, Igboho ní káwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ Yorùbá lọ múra ògùn jọ nítorí ohun tó ń bọ̀ lọ́nà
- Ọlọrun má jẹ́ kí a jẹ́ gbèsè lókù báyìí tí a kò kó ọjá lọ sílẹ̀ Yorùbá mọ́- Hausa Oníṣòwò
- Ẹni tó tẹ̀é mi lọ sílé ẹjọ́ ti ayé ń pariwo kìí ṣe Aláfọ̀ṣẹ rárá bíkòṣe...- Sowore
Bakan naa ni wọn yoo tun gbajumọ rira awọn ohun eelo ijagun, ohun eelo ikọni ati idanilẹkọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo.
Hadi Sirika salaye eyi fun awọn akoroyin lẹyin ipade rẹ pẹlu aarẹ Muhammadu Buhari lataari abẹwo rẹ si ipinlẹ Zamfara.
Lọjọ Abamẹta to kọja ni Hadi Sirika ṣaju awọn ikọ kan lọ si ipinlẹ Zamfara.
Bakan naa nijọba paṣẹ fun awọn ajọ ẹṣọ ara ilu Nigerian Security and Civil Defence Corps (NSCDC) lati tubọ ri si eto aabo awọn akẹkọọ.
- Chimamanda Adichie pàdánù bàbá, ìyá láàrín ọdún kan, kíló ṣẹlẹ̀?
- Ẹ wo bí ìyàwó Pasitọ Adeboye ṣe sàpèjúwe rẹ̀
- Kí làwọn nǹkan tó lè rán ọkùnrin sí ọ̀run alákeji lásìkò ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin?
- Wo ibi tí o ti lè fi orúkọ síìmù rẹ sílẹ̀ tàbí gba nọ́mbà tuntun tí síìmù rẹ bá sọnù
- Owó Taxi ní ìpínlẹ̀ Ondo tí padà sí N50 látí N100 nítorí kò sí gbígba ''tíkẹ́ẹ̀tì'' NURTW mọ́
Àwọn ajínigbé fìyà jẹ́ wa lọ́nà igbó tí wọ́n kó wa lọ- Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin GSS Zamfara:
Àwọn ajínigbé ní àwọn á yìnbọn pa wá tí a kò bá tètè rín nínú igbó-Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin GSS Zamfara
Awọn Ajinigbe fiya jẹwa lọna nigba ti wọn n gbe wa lọ si inu aginju-Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin GSS Zamfara

Oríṣun àwòrán, @Zamfara Govt
Koda. Wọn tilẹ ni awọn yoo yinbọn pawa, ti a ko ba rin kiakia lọna igborere ọhun.
Awọn ọmọbinrin ileewe GSS Jangebe ni Zamfara lo sọ iriri wọn lọwọ awọn agbegbn to jiwọn gbe.
Awọn ọmọ yii royin ohun ti oju wọn ri to fun ijọba Zamfara lẹyin ti wọn doola ẹmi wọn.
Bakan naa ni Aarẹ Buhari ni iriri awọn ọmọbinrin to fẹrẹ tọ ọọdunrun naa kọja keremi
Ọjọ Keji, Oṣu Kẹta ni ijọba ipinlẹ Zamfara kede itusilẹ wọn lọwọ awọn ajinigbe.
A kò san owó ìtanràn kankan látí gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin yìí- Gomina Zamfara
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin ilé ẹ̀kọ́ GSS ní ìpínlẹ̀ Zamfara ti gbòmìnira lọ́wọ́ àwọn ajínígbé
Gomina ipinlẹ Zamfara, Bello Matawalle ti sọ fun BBC pe ijọba oun ko san owo itanran kankan lati gba awọn akẹkọọbinrin ti awọn ajinigbe ji gbe naa pada.
O ni awọn kan jọ ni ajọsọpọ pẹlu awọn ajinigbe naa ni.
Bakan naa ni gomina naa fidiẹ mulẹ pe gbogbo awọn akẹkọọ naa lo ti gba ominira ati pe inu oun dun fun ominira awọn ọmọbinrin 279 naa.
Gẹgẹ bi o ti hande pe awọn alaṣẹ orilẹ-ede Naijiria kii gba lọpọ igba pe wọn san owo itanran fun awọn ajinigbe.
Lọjọ Eti to kọja ni awọn agbebọn kọlu ile ẹkọ GSS Jangebe lati ṣọṣẹ yii.
- Ẹ wo èrò àwọn ènìyàn lórí bí Gòmìná Akeredolu ṣe fòfin de NURTW, RTEAN nípínlẹ̀ Ondo
- Ọkùnrin méjì dèrò àhámọ́ lẹ́yìn tí wọ́n fipá bá ọmọ ọdún 16 lòpọ̀
- Fáàbàdà! Ìjọba mi kọ́ ní yóò buwọ́lu ìgbéyàwó akọ sákọ àti abo sábo- Ààrẹ Ghana yarí
- Ẹ tú ìgbéyàwó wa ká, níṣe n'ìyàwó mi máa ń gbá mi létí- ọkùnrin kan sọ fún iléẹjọ́
- Wo bí o ṣe lè forúkọsílẹ̀ láti gba abẹ́rẹ́ àjẹsárá Covid-19 lẹ́yìn to bá dé sí Naijiria

Oríṣun àwòrán, Twitter
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 279 ti ilé ẹ̀kọ́ GSS ní ìpínlẹ̀ Zamfara ti gbòmìnira lọ́wọ́ àwọn ajínígbé
Awọn akẹkọọbinrin ti wọn jigbe ni agbegbe Jangebe ni ipinlẹ Zamfara ni wọn ti gba ominira bayii
Kọmiṣọnna fun eto aabo abẹle ni ipinle Zamfara fidiẹ mulẹ fun BBC.
O ni awọn akẹkọbinrin 279 to jẹ ọkan dinlọgọrin o le ni igba ni awọn ti ri gba pada bayii.
Koda awọn akẹkọbinrin naa ti wa ni Gusau to jẹ olu ilu ipinlẹ Zamfara.
Kọmisọnna ọrọ abẹlẹ naa tun fidiẹ mulẹ fun BBC pe kii ṣe ọmọ 317 to jẹ mẹtadinlogun le ni ọọdunrun ti wọn kọkọ ni awọn ajinigbe gbe ni wọn ji gbe.
O ni ko si ọmọbinrin kankan mọ ni akata awọn ajinigbe naa mọ.
O ni gomina yoo ba wọn sọrọ laarọ oni.
Lọjọ Eti ni wọn ji awọn ọmọ naa gbe ni agbegbe Jangebe ni ipinlẹ Zamfara to wa ni ariwa Naijiria.
A ko le fidiẹ mulẹ boya wọn san owo itanran tabi bẹẹkọ.
- Àwọn jàndùkú ajínigbé fẹ́ẹ̀ lù wá pa nínú igbó, ọ̀rọ̀ rèé lẹ́nu àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ ìlú Kagara
- Mo kọ̀ láti gbọ̀jẹ̀gẹ́ tàbí bẹ̀rù ẹnikẹ́ni nítorí ìjà òmìnira ìran Yorùbá- Igboho
- Bí èèrà lásán bá rin Sunday Igboho, ẹ rugi oyin - Oodua Youth Caolition
- Wo àwọn ìlú tó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti èèwọ̀ ni kí ènìyàn kú níbẹ̀
- Wọ́n ní ọkọ̀ bàálù NAF tó mú ẹ̀mí ọmọ mi lọ l'Abuja ti lo ọdún 49 láyé - Bàbá Flight Sergent Olasunkanmi
- Láti 1978 tí Bàbá mi ti jẹ Oba ni mo ti mọ̀ pé máà jẹ adelé- Margret Omonije
BBC Yoruba yoo maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin ọhun wa fun un yin bo ba ṣe n lọ....
























