Ipaniyan Zamfara: Ile isẹ ọlọpaa kede mimu afurasi meta

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG
Ile iṣẹ ọlọpaa ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ afurasi mẹta ti wọn jẹ agbatẹru ipaniyan to waye ni ipinlẹ Zamfara.
Alukoro ile isẹ ọlọpaa, Moshood Jimoh lo lede ọrọ naa ninu atẹjade kan.
Eniyan ogun lo padanu ẹmi wọn ninu ikọlu to waye labule Birane ni ijọba ibilẹ Zurmi lọsẹ to kọja ni Zamfara.
Moshood Jimoh ni orukọ wọn ni Halilu Garba, ọmọ ọdun marundinlaadọta ti inagijẹ rẹ njẹ Mabushi, Zubairu Marafa, ọmọ ọdun marundinlaadọta ti wọn mọ si Wakili ati Nafiu Badamasi, ọmọ ogoji ọdun ti wọn tun maa n pe ni Zakiru.
Moshood Jimoh ni ọga olopaa ti ṣaaju paṣẹ fun ikọ apapọ ọtẹlẹmuyẹ eleyi ti ọga agba ọlọpaa fun ikọ ọtẹlẹmuyẹ ko sọdi lati lọ si Zamfara ki wọn si bẹrẹ iwadi lori isẹlẹ ipaniyan to waye nibẹ.








