Students abduction, Kagara GSC Students: Ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ láwọn ò padà lọ sílé ẹ̀kọ́ wọn mọ́ torí ohun tí ojú wọn rí lákàtà ajínigbé

Awọn akẹkọọ ilu Kagara

Oríṣun àwòrán, Twitter/Governor Niger

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Iroyin ko to amojuba lẹnu awọn akẹkọọ ile ẹkọ girama ilu Kagara nipinlẹ Niger to ṣẹṣẹ gbominira lọwọ awọn ajinigbe lọjọ Abamẹta ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu keji ọdun 2021.

Gomina ipinlẹ Niger, Abubakar Sani Bello lo tẹwọ gba awọn akẹkọọ atawọn oṣiṣẹ ile ẹkọ naa ti gbogbo wọn jẹ mejildinlogoji.

Ọkan lara awọn akẹkọọ naa Abubakar Sidi, ọmọ ogun ọdun to wa ni kilaasi SS3 ṣalaye pe awọn janduku ajinigbe ọhun fiya jẹ awọn nipasẹ iṣẹ ti obi ẹni kọọkan awọn n ṣe.

''Wọn ko fun wọn lounjẹ lati ago kan ọsan to fi di oru ki wọn to pada fun wa lounjẹ.

Lẹyin ti wọn fun wa lounjẹ tan, wọn bẹrẹ si ni sọ fun wa pe ki awọn ti baba wọn ba jẹ ọlọpaa ati sọja bọ sita, eyi lo maa sọ iru iya ti wọn maa fi jẹ wọn,'' Sidi ṣalaye.

Àkọlé fídíò, Regent Ondo: Láti 1978 tí Bàbá mi ti jẹ Oba ni mo ti ms pé máà jẹ adelé- Magaret Omonije I

Akẹkọọ miran, Suleiman Lawal toun naa wa ni kilaasi SS3 ṣalaye pe ''awọn ajinigbe fiya jẹ wa debi pe n ko ro pe mo le pada si ilẹ ẹkọ wa mọ.''

Awọn akẹkọọbinrin to wa lara awọn akẹkọọ naa ko tiẹ le sọrọ rara fun ẹru to si wa lara wọn.

Awọn akẹkọọ ilu Kagara

Oríṣun àwòrán, Twitter/Governor Niger

Ọpọ awọn obi to ba awọn akọroyin naa sọ pe awọn le maa jẹ ki awọn ọmọ awọn pada si ile ẹkọ naa mọ.

Arabinrin Elizabeth Jonathan to jẹ ọkan lara awọn obi awọn akẹkọọ ti wọn jigbe ni oun ko le sun fun ọjọ mọkanla tawọn akẹkọọ naa fi wa lakata awọn ajinigbe.

Àkọlé fídíò, Femi Falana, Endsars: Awolowo kò fáààyè gba kí èèyàn máa yàgò fún Màálù nígboro

''Ayọ mi kun wi pe ọmọ mi ti kuro lọwọ awọn ajinigbe, ko ni pada si ile ẹkọ naa mọ,'' Arabinrin Jonathan lo sọ bẹẹ.

Ẹwẹ, Gomina Bello ipinlẹ Niger ti kede pe ijọba n gbero lati gbe awọn ile ẹkọ tawọn akẹkọọ n sun ti pa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Àkọlé fídíò, Mother tongue day 2021, Akomolede, YSAN: A ti parí iṣẹ́ lórí èdè ìperí Meta-Language Yorùb

Gomina ipinlẹ Niger sọ pe gbogbo eeyan mejidinlogoji ti wọn jigbe ni wọn ti gba itọju nile iwosan.

Gomina Bello fikun ọrọ rẹ pe ọkan lara awọn akẹkọọ mẹtalelogun to ṣẹṣẹ gbomina lọwọ awọn ajinigbe si tun wa nile iwosan tori ailera rẹ.

Àkọlé fídíò, Badagry Historical Wells: Omi inú kànga Wawú ló ń kó ọpọlọ àwọn ẹrú lọ