Sunday Igboho and Gani Adams: Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò

Oríṣun àwòrán, @_IgbohoSunday
Ajafẹtọọmọniyan ati ajijagbara, Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti ṣabẹwo si Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Gani Adams, ni ile rẹ to wa niluu Eko.
Bo tilẹ jẹ pe a ko le sọ ni pato eredi ipade ọhun, ṣugbọn ọpọ awọn ọmọ Yoruba lo ti bẹrẹ si n sọ pe ipade ọhun ko ṣẹyin ọrọ eto abo ilẹ Yoruba ati awọn Fulani darandaran.
Ẹ wo awọn aworan bi ipada naa ṣe lọ.

Oríṣun àwòrán, @_IgbohoSunday

Oríṣun àwòrán, @_IgbohoSunday

Oríṣun àwòrán, @glamtush

Oríṣun àwòrán, @NewsExtremists

Oríṣun àwòrán, @upshotreports
Mo kọ̀ láti gbọ̀jẹ̀gẹ́ tàbí bẹ̀rù ẹnikẹ́ni nítorí ìjà òmìnira ìran Yorùbá- Igboho
Sunday Igboho ti ṣọkan akin nipa ohun to n ṣẹlẹ sii alsiko yii.
O ni oun ko ni bẹru bẹẹ si ni oun ko ni gbọjẹgẹ rara lori ọn aominira iran Yoruba.

Oríṣun àwòrán, @joeshooar
Ajijangbara yii ni o ya oun lẹnu pe ko sohun to tilẹ jọ pe ọlọpaa kọkọ pe oun fun ifọrọwanilẹnuwo.
Ẹwẹ, Sunday Igboho ṣalaye pe oun ko mọ idi ti wọn fi n wa oun kiri o si gba ijọba nimọran pe ki wọn gbajumọ eto aabo ilẹ Naijiria.
O ni kji wọn kọkọ lọ mu adari ikọ Boko Haram, Abubakar Shekau na, ki wọn si kọwe ranṣẹ pe Sheikh Gumi Ahmad Gumi to ti n ṣepade pẹlu awọn ajinigbe laipẹ yii.
- Wo oríṣi oúnjẹ márùn ún tí kò wọ́pọ̀ ṣùgbọ́n tí àwọn kan fẹ́ràn púpọ̀ ní Nàìjíríà
- Irọ́ ni pé wọ́n ti fi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kagara sílẹ̀- Gomina ìpínlẹ̀ Niger
- Ìjọba ti ileẹ̀kọ́ pà lẹ́yìn tí àwọn jàndùkú ṣèkọlù sí Osogbo, ìpínlẹ̀ Osun
- Àwọn obìnrin mánigbàgbé tó ti kópa nínú sáà ìjọba tiwantiwa láti ọdún 1999
- Àwọn obìnrin mánigbàgbé tó ti kópa nínú sáà ìjọba tiwantiwa láti ọdún 1999
Bí èèrà lásán bá rin Sunday Igboho, ẹ rugi oyin - Oodua Youth Coalition
Tí Sunday Igboho bá kó sọ́wọ́ ìjọba, ẹ bi àwọn àgbàgbà Yoruba léèrè - Oodua Youth Coalition
Ẹgbẹ awọn ọdọ ọmọ Yoruba, iyẹn Oodun Youth Coalition, OYC, ti kilọ fun ijọba apapọ pe eera kankan ko gbọdọ rin Oloye Sunday Ageyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho.
Ẹgbẹ naa koro oju si igbiyanju awọn agbofinro lati fi pampẹ ofin mu Sunday Igboho loju ọna marosẹ Eko ti Ibadan lọjọ Ẹti.
Ninu atẹjade kan aarẹ ẹgbẹ ọhun, Tayo Oluyi Akintade fi lede, o ni awọn ko ni gba ki ijọba halẹ mọ Sunay Igboho, tabi ki wọn jii gbe.
Akintade tẹsiaju pe awọn agbagba Yoruba ni awọn yoo di ẹbi ọrọ naa le lori ti ijamba kankan ba ṣẹlẹ si ajafẹtọ ọhun.
Aarẹ OYC tun bu ẹnu ẹtẹ lu awọn awọn oṣiṣẹ eto abo lori akitiyan wọn lati mu Sunday Igboho nigba ti wọn ko ṣe bẹẹ lori ọrọ awọn ajinigbe.
O ni "o jẹ ohun iyalẹnu fun wa nigba ti a ri fidio bi wọn ṣe gbiyanju lati mu Oloye Sunday Igboho."
"O ṣeni laanu pe wọn gbiyanju lati mu ajijagbara naa ṣugbọn wọn ko da si ọrọ awọn ọmọ ile ẹkọ ti awọn kan ji gbe lọ laipẹ yii."
Akintade tẹsiwaju pe ko ni jẹ ohun iyalẹnu fun awọn ti ọkan tabi meji lara awọn agbagba ilẹ Yoruba ba mọ si igiyanju ijọba lati mu Sunday Igboho."
O pari ọrọ rẹ pe OYC ti bẹrẹ si n ṣo awọn agbagba ilẹ Yoruba loju mejeji, ati pe awọn yoo di ẹbi ọrọ naa le wọn lori ti ohunkohun ba le ṣẹlẹ si Sundsay Igboho

Sunday Igboho fohùn ráńṣẹ́ sí ìjọba Nàìjíríà lórí bí Ọlọ́pàá ogójì ṣe wá mú u
Ajijangbara ilẹ Yoruba, Sunday Adeyemo ti ọpọ n pe ni Sunday Igboho ti fohun sita pe oun ko ni gba ọjẹgẹ rara, oun o si ni bẹru igbesẹ awọn ọlọpaa.
Eyi waye gẹgẹ bi ẹka ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa ṣe paṣẹ pe ki wọn gbe e amọ o ni gbogbo akitiyan wọn ni yoo kuna.
Igboho sọ ọrọ naa ninu ifọrọwanilẹnuwo kan nigba to n fesi si bi awọn ọlọpaa ṣe kọlu u lagbegbe ile ijọsin Guru Maharaji lopopona Eko si Ibadan.
Sunday Igboho ní ó tó ogójì àwọn ọlọ́pàá tó dènà dé òun- Femi Fani-Kayode
Ẹgbé ìsòkàn ọmọ Yorùbá Afenifere ti bẹnu àtẹ́ lu ìgbìyànjú àwọn elétò ààbò láti mú Sunday Adeyemo, ti gbogbo ènìyǹ mọ̀ si Sunday Igboho.
Agbẹnusọ ẹgbẹ Afenifere, Yinka Odumakin sọ pé àwọn irinṣẹ́ ìjọba ko ni lépa Sunday Igboho to bá jẹ́ pé ọdaran ni.
Odumakin sàlàyé pé: Kò sí ìwà ọpọlọ nínú ìgbìyànjú rẹ̀ láti mú Igboho, ọmọ Naijiria ni ọ si yẹ ki o le wà ni òmìnira. Ti wọn bá nílò rl, ó yẹ ki wọ́n pèé fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nù wò ni kìí ṣe pé ki wan máá dènà dèé bí ìṣe àwọn ọ̀gárá ọlọ́ṣà.
- 7 nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 317 tí wọ́n jí gbé ní GGSS Jangebe sá mọ́ àwọn ajínigbé lọ́wọ́
- Àwọn ọmọ mi ṣi kéré jọjọ, kò sí ẹni ti yóò gbé ẹru mi- Ìyàwó olóògbé
- Wo ohun 10 tó yẹ́ kó mọ̀ nípà Abdulrasheed Bawa ẹni ọdun 40 tó di ọ̀gá EFCC tuntun
- Nkechi Blessing àti Bobrisky fìjà pẹ́ẹ́ta nítori ọ̀rọ̀ "Tattoo"
- Arapa re gangan sọ̀rọ̀ nípa ìrìnàjò ìpè rẹ̀ tuntun
"A bu ẹnu àtẹ́ lu irú ìwà yìí, kò nílò kí ìjọba ṣe irú rẹ̀. Wọn kò tilẹ̀ pé rárá débi ti wọ́n yóò sọ pé kò dá àwọn lóhun .
Afenifẹre ni ìjọba Muhammaedu Buhari buyì fún àwọn jàndùkú ti wan n yan fànda kiri igboro lẹyinti wọ́n ba pa ará ìlú lẹ́kún tán jú ara ilú tó n bọ̀wọ̀ fún òfin lọ.
Ẹ̀wẹ̀, Ilé iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ ti fi àtẹ̀jáde síta láti ọwọ́ agbẹnusọ ilé iṣẹ náà Peter Afunanya, Ph.D sọ pé, ìròyìn òfégè ni, àwọn kò mọ̀ ǹkankan nípa ìgbìyànjú láti fi panpẹ́ ọba mú Sunday Igboho ní ìlú Ibadan lónìí.
Ó ni òfẹ́gè ni ìròyìn náà kò sí òtítọ́ níbẹ̀.
Bákan náà ni Femi Fani-Kayode ti fi ipe síta pé òun ti bá Sunday Igboho sọ̀rọ̀, ó sì sàláyé pé o tó ọlọ́paà ogójì tó dènà de òun
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Wàhálà bẹ́ sílẹ̀ bi DSS, ọlọ́pàá ṣe fẹ́ mú Sunday Igboho lópòpónà márosẹ̀ Lagos-Ibadan
Dàrúdápọ̀ bẹ́ sílẹ̀ ní òpópónà máròṣẹ̀ Lagos-Ibadan lọ́jọ́ lọ́sàn òní ọjọ́ Eti, ọjọ́ kẹrìndílọ́gbọ̀n oṣù kejì, ọdún 2021, nígbà ti àwọn ọlọ́pàá àti àwọn ọmọ ọtẹ̀lẹ̀ múyẹ gbìyànjú láti mú ajàjàgbara ọmọ ilẹ̀ Yorùbá, Sunday Igboho.

Gẹ́gẹ́ bi fọ́ran kan ti o tẹ́ BBC lọ́wọ́ láti ọwọ́ agbẹnusọ rẹ̀ Olayọmi Koiki tó sì sàlàyé pé, olóyè Sunday Igboho n bọ lati ibi ìpàdé kan nílùú Eko, sùgbọ́n nígbà tó dé àgbègbe Sat Guru Maraji ni àwọn ọlọ́pàá dédé bòwan láti mú òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀.
- Èèmọ̀ wọ̀lú, agbébọn jí ajá tí iye rẹ̀ tó mílíọ̀nù 1,906,250.00 gbé lójú ìbọn, ó dèrò ilé ìwòsàn
- Nkechi Blessing àti Bobrisky fìjà pẹ́ẹ́ta nítori ọ̀rọ̀ "Tattoo"
- Wo ìlú márùn-ún tó ń bọ tàbí sin ejò bí ọlọ́run, ṣé ìlú rẹ̀ wà lára wọn tí o kò mọ̀?
- Fayemi ló tó gbangba sùn lọ́yẹ́ láti jẹ ààrẹ Nàìjíríà lọdún 2023- Àwọn lọ́balọ́ba Ekiti
Gẹ́gẹ́ bi o ṣe sọ àti bí fọ́ran náà ṣe fi hàn, olóyè Sunday Igboho bọ́ asọ rẹ̀ sílẹ̀ tó sì kójú àwọn ọlọ́pàá náà.
Gẹ́gẹ́ bi a ṣe gbọ́ nínú fọ́nran náà ti olóye Sunday Adeyemi fúnra rẹ̀ si fi ìdí ọ̀rọ̀ ọ̀hún múlẹ̀ nínú pé lóòta ni àwọn ọlọ́pàá dènà de òun, yálà bóyá wọ́n n sọ òun ni tàbi ẹnìkan ta wọ́n lolobo.

Nínú fọ́ran òun ní a ti ri olóyè Sunday Igboho tó ti bọ́ asọ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ ti wọ́n sì kójú sí àwọn ọlọ́paà.
Gẹ́gẹ́ bi àtẹjáde ti mínísítà fún ọ̀rọ̀ ìrìnà òfurúfú nígbà kan rí, Femi Fani -Kayode sàlàyé pé Sunday Ighoho n bọ láti ibi ìpàdé pẹ̀lú olóyè Ayo Adebanjo lásìkò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀.
Bákan náà ni BBC Yoruba bá agbẹnusọ rẹ̀ míràn Oladapo Salami to si fi ìdì ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ pé lóòtọ́ ni àti pé Olóyè Sunday ti wà nílé báyìí tó sì wà ni alááfíà.




















