Lady Gaga Net worth: Ǹkan ti a mọ̀ nípa bí Lady Gaga ṣe rí ajá rẹ̀ padà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìròyìn sọ pé àwọn ajá olówó iyebíye Lady Gaga ti wọ́n jí gbé lánà lójú ìbọ̀n ti padà sílé láyọ̀ àti àláfíà gẹ́gẹ́ bi àwọn ọlọ́pàá ṣe sọ.
Lásìkò ìdigunjalè ni àwọn agbébọn já wọ́n gbé sùgbọ́n wọ́n ti dáwọn pada fún àsoju gbájúgbàjà olórí náà.
Ẹni to máa n ran Lady Gaga lọ́wọ́ láti mú àwọn ajá náà rìn Ryan Fischer ni àwọn ọ̀daràn méjì náà yìnbọn lù ti wọ́n si jí àwọn ajá náà ni Hollywood, Los Angelis lọ́jabọ
Ni báyìí o ti wà nílé ìwòsàn tó ti n gba ìtójú, àwọn ẹbi rẹ náà fi ìdí rl múlẹ̀ pé ìrètí wà pé ara rẹ yóò ya ni àìpẹ́.
- Sunday Igboho ní ó tó ogójì àwọn ọlọ́pàá tó dènà dé òun- Femi Fani-Kayode
- Àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ nínú fídíò tó ń tàn ká lórí ayélujára kìí ṣe olùkọ́ tàbí akẹ́kọ̀ọ ́LAUTECH"
- Èèmọ̀ wọ̀lú, agbébọn jí ajá tí iye rẹ̀ tó mílíọ̀nù 1,906,250.00 gbé lójú ìbọn, ó dèrò ilé ìwòsàn
- Ẹ gbọ́ ohun tí àwọn ọmọ Naijiria ń sọ lẹ́yìn tí àwọn ajìjàgbara Niger Delta ṣèlérí láti kọlu Eko àti Abuja
Báwo ni wọ́n ṣe ri ajá náà gbà padà?
Bi wọ́n ṣe ri ajá náà padà ko ni alàyé kan ni pàtó, sùgbọ́n ìwé ìròyìn Associated Press sọ pé, obìnrin kan lo kan mú wọ́n wá si agọ ọlọpàá to wa ni agbègbè Olympic ni Los Angels ti asojú gbájúgbajà olórín náà sì sọ pé ajá àwọn ni.
Obìnrin náà ko jọ pé ó ms nípa àwọn ọdaran náà, gẹ́gẹ́ bi agbẹnusọ ọlọ́pàá ṣe sọ.

Oríṣun àwòrán, Lady Gaga
Sáájú ni Lady Gaga ti jẹ́ẹ́jẹ́ pé òun yóò fún ẹni kẹni tó bá ri àwọn àjá náà ni ($500,000) (#241,000,000) gẹ́gẹ́ bi ẹbùn.
Lady gaga ti orúkọ rẹ̀ gán ń jẹ́ Stefani Germanotta wa ni Rome nibi tó ti n se fíìmù tuntun.
Aná ni ìgbà akọ́kọ́ tó sọ̀rọ̀ lóri ijígbé ajá náà nínú ọ̀ọ̀ tó kọ sójú òpó twitter rẹ̀
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Èèmọ̀ wọ̀lú, agbébọn jí ajá tí iye rẹ̀ tó mílíọ̀nù 1,906,250.00 gbé lójú ìbọn, ó dèrò ilé ìwòsàn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wọn ti ji aja gbajugbaja olorin Lady Gaga gbe lẹyin ti awọn agbebọn kan yinbọn lu ẹni to maa n mu awọn aja naa rin lagbegbe Holywood, ni Los Angeles.
Iroyin ni agbebọn ọhun yinbọn lu ẹni to n mu aja naa rin ko to ji aja meji ọhun gbe lọ.
Ileeṣẹ ọlọpaa l'Amẹrika fi to akọroyin BBC leti pe wọn ti gbe ẹni to maa n mu aja naa rin lọ si ile iwosan kan ti wọn ko darukọ rẹ lẹyin iṣẹlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Lady Gaga / Instagram
Lady Gaga ti kede pe oun yoo fun ẹnikẹni to ba mọ bi oun ṣe le ri awọn aja ọhun, ti orukọ wọn jẹ Koji ati Gustav, ni ẹbun iyebiye.
Aja kẹta ti orukọ rẹ n jẹ Miss Asia sa asala mọ agbebọn naa lọwọ, awọn ọlọpaa si ti ri i.
Lady Gaga, ti orukọ abisọ rẹ n jẹ Stefani Germanotta wa ni ilu Rome lọwọlọwọ, nibi to ti n ṣiṣẹ lori fiimu kan ti wọn pe ni Gucci.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gaga ni oun yoo fun ẹnikẹni to ba le ṣamọna bi awọn aja ọhun yoo ṣe di riri ni $500,000 gẹgẹ bii owo ifẹmiimoore han.
Bo tilẹ jẹ pe a ko lee sọ boya agbebọn yii ṣakọlu si Lady Gaga nitori ipo to wa laarin ilu ni tabi irufẹ aja to ni.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn agbebọn yoo ji aja gbe nilẹ Amẹrika.
Fun apẹrẹ, awọn ọkunrin mẹta kan ṣakolu si obinrin kan ni San Francisco loṣu kinni ọdun yii, ti wọn si gba ọmọ aja to wa lọwọ rẹ loju ibọn.















