LAUTECH Sex Video: A kò mọ àwọn tó wà nínú fídíò ìbálòpọ̀ t́i àwọn èèyàn n gbé kiri rí

LAUTECH Sex Video: A kò mọ àwọn tó wà nínú fídíò ìbálòpọ̀ t́i àwọn èèyàn n gbé kiri rí

Oríṣun àwòrán, Lautech

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ fasiti Ladoke Akintola to wa ni Ogbomosho, LAUTECH, sọ pe ọkunrin ati obinri to ni ajọṣepọ ninu fidio kan to mi ayelaura titi kii ṣe ọkan lara awọn olukọ tabi akẹkọọ awọn.Ninu fidio naa to jade lori ayelujara lọjọbọ, ọkunrin naa ati omidan ọhun n ni ibalopọ lori ibusun, ti ẹnikan si kan ilẹkun.Lẹyin ti omidan naa ni ki ẹni to n kan ilẹkun wọle ni ọkunrin to n baa ni ibalopọ funra pe wọn n ka ibalopọ wọn silẹ.

Àkọlé fídíò, 'Tí mi ò bá rí ògùn rà fún ọmọ mi, á máa gé ara rẹ̀ jẹ tí ẹ̀jẹ̀ yóò máa ṣàn'

Oṣiṣẹ LAUTECH kan to ba awọn akọroyin sọrọ, ṣugbọn ti ko fẹ ki wọn fi orukọ oun lede sọ pe ohun iyalẹnu nla lo jẹ fun fasiti naa pe awọn kọlọrọsi kan n fi iṣẹlẹ naa ba awọn lorukọ jẹ.Oṣiṣẹ naa sọ pe awọn alaṣẹ fasiti ọhun ti ke si adari ẹka imọ agbẹ atawọn adari ẹka miran, ti gbogbo wọn si ni awọn ko mọ ọkunrin to wa ninu fidio naa ri.O ni "a n fi akoko yii pe awọn to ba ni ẹri aridaju pe oṣiṣẹ wa ni ọkunrin naa tabi pe akẹkọọ wa ni omidan naa lati wa sọ ni gbangba pẹlu ẹri to dantọ.""Ọpọlọpọ iwadii ijinlẹ ati aṣeyọri ni a ti ṣe ni fasiti yii ti awọn eeyan ko mẹnuba, ṣugbọn wọn kan n ba wa lorukọ jẹ kiri ni." Ṣaaju ni alaga igbimọ ẹgbẹ awọn akẹkọọ ni Naijiria, ẹka ti ipinlẹ Oyo, Mayowa Opakunle ti kọkọ kede pe awọn akẹkọọ ati oṣiṣẹ LAUTECH ko mọ ẹnikankan ninu awọn eeyan naa to ni ibalopọ ninu fidioa ọhun.Opakunle to jẹ akẹkọọ nipa imọ ọja tita ni LAUTECH sọ pe inu awọn akẹkọọ fasiti naa ko dun nitori bi awọn eeyan kan ṣe n gbe igbesẹ lati ba orukọ fasiti naa jẹ.Gẹgẹ bo ṣe sọ, "ọkunrin to wa ninu fidio yẹn kii ṣe olukọ ni LAUTECH bẹẹ si ni omidan yẹn kii ṣe ọkan lara awọn akẹkọọ wa.""A ti wo fidio naa lọpọ igba, a si fẹ fi asiko yii sọ fun awọn eeyan pe awọn to wa ninu fidio yẹn ko ni nnkankan ṣe pẹlu fasiti wa.""Emi funra ni mi ni mo maa bẹrẹ ifẹhonuhan to ba jẹ pe lootọ ni obinrin yẹ jẹ akẹkọkọ wa, ti ọkunrin naa si jẹ ọkan lara awọn olukọ wa, ṣugbọn irọ ponbele ni."Opakunle pari ọrọ rẹ pe awọn ti fi ẹjọ awọn to fi fidio naa lede sun ileeṣẹ Twitter ki wọn le da seria fun wọn.