Plane Crash: Mi o mọ ibi tí ń o ti bẹ̀rẹ̀, àwọn ọmọ mi ṣì kéré- Aya Olóògbé

Ní ọjọ́ Aiku, ogunjọ́ oṣù kejì ọdún yìí ni ìṣẹ̀lẹ̀ aburu kan ṣẹ ti gbogbo ariwo si gbá oeílẹ̀-èdè Naìjíríà kan.
Láàrín wákàtí díẹ̀ ni ìròyìn n tà ka pé àwọn ọmọ ogun ojú ofurufu kan ni ọkọ̀ wọ́n já ni kété ti wọ́n gbéra tan ni pápákò òfurúfú ìlú Abuja.
Sáájú kò si ẹni tó yé irú àwọn ènìyàn mtó wà nínú ọkọ̀ ofúrúfu ilé iṣẹ́ ọmọogun náà, sùgban ìròyìn fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ènìyàn méjè ló wà níbẹ̀.
Sùgbọ́n nígbà tí ilẹ̀ yóò fi ṣú ni ọjọ́ náà ariwo ẹkún sọ nínú ilé ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn.
Lára àwọn ìdílé náà ni ti Flight Sergent Olawumi Olasunkanmi tí ìyàwó rẹ̀ bá BBC News Yoruba sọ̀rọ̀ lórí àwọn ǹkan tí ó ṣelẹ̀ kí wọ́n tó kéde àwọn tó wà nínú ìjàmbá ọkọ̀ náà
Gẹ́gẹ́ bi aya olóògbé ṣe sọ, ní jété ti àwọn ti ṣọ́ọ̀ṣì dé ni ọjọ́ náà ni àwọn ọmọ sọ pé, àwọn fẹ́ bá bàbá àwọn sọ̀rọ̀, ó ni lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ náà ni òun sì mu fóònù láti pèé.

Oríṣun àwòrán, NAF
"Bí mo ṣe pèé ló ni a ti n méra láti gbera ni Abuja báyìí, má ppe yí ti mo bá ti gúnlẹ̀" Ǹkan tí a jọ sọ gbẹ̀yìn r['e a fi ti mo gbọ́ pẹ́ báàlú wọ́n já."
Aya olóògbé ní àwọn ọmọ òun kéré gidi gan ni àti pé ọkọ òun nìkan lo n gbe gbogbo bùkátà ilé.
O ní olóógbé fẹ́ràn àwọn ọmọ rẹ gidi ni, owó ilé iwé, owó ilé kò sí ẹni ti yóò san mọ́.
"Iranlọ́wọ́ ni mo fẹ́ lati ọwọ́ ìjọba , láti dá si ọ̀rs owó ilé iwé àwọn ọmọ títí dé fásitì"

Bákan náà ni màmá olóógbé sọ tirẹ̀ pé òun ti ni àbíkú àgbà. O ní gbogbo ọ̀nà ni òun fi pàdànú.
"Kò sí aábárò tàbi olùbádámọ̀ràn mọ́. Ìya náà ni olúọmọ òum ló ku yìí àti pé ààyè òun ti sófo láwùjọ"
Bàbá Olawumi, àti àbúrò rẹ̀, to fi mọ́ káàbíyèsí ìlú rẹ ló ròyìn pé, olú ọmọ tó yẹ ki o gbé ogo ìlú ga lo ku lójijì.
Wọ́n wa rọ ìjọba àpapọ láti dide ìrànlọ́wọ́ sí ẹbí olóògbé tó ku sí ẹnu iṣẹ́ láti ran àwùjọ lọ́wọ́.

Oríṣun àwòrán, NAF













