LAUTECH sacked staff: Makinde dá àwọn LAUTECH 41 tí Ajimobi dá dúró padà sẹ́nu iṣẹ

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/LAutech

Makinde gba àwọn òṣìṣẹ́ LAUTECH 41 tí ìjọba Ajimobi dá dúró lẹ́nu iṣẹ́ padà

Ijọba ipinlẹ Oyo ti gbawọn ọṣiṣẹ fasiti LAUTECH ilu Ogbomosho mọkanleloji ti ijọba to lọ da duro lẹnu iṣẹ.

Igbesẹ yii jẹ ọkan awọn ohun to ṣẹlẹ nibi Ipade igbimọ alaṣẹ ipinlẹ Oyo.

Kọmiṣọnna eto iroyin, aṣa ati Irin-ajo igbafẹ ipinlẹ Oyo, Ọmọwe Wasiu Olatunbosun lo fidi ọrọ yìi múlẹ ninu atẹjade kan to fi sita lorukọ ijọba ipinlẹ Oyo.

O ni igbesẹ yii wa ni ibamu pẹlu Ipinnu Gomina Makinde lati lati mu igbayegbadun awọn eeyan ipinlẹ Oyo lọkunkundun.

Ọmọwe Olatunbosun ni ati inu oṣu karun un, ọdun 2020 tawọn akẹgbẹ wọn ti wọn da duro lẹnu iṣẹ pada ni ijọba yoo ti bẹrẹ sí ni kaa fawọn naa.

Ko ṣai rọ awọn eeyan naa lati kọju mọ iṣẹ wọn ju ti at'ẹyin wa lọ nibayii ti won ti pada sẹnu iṣẹ.

Ijọba Gomina Seyi Makinde tun Kede pe ki wọn san owo oṣu marun un fawọn oṣiṣẹ ọhun.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC: Kí ní ìtúmọ̀ Sílébù àti àmi ohun tó ń fún ni?