Death penalty for rapists: Wo ìpínlẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ buwọ́lu ìdájọ́ ikú f'ẹ́nikẹ́ni tó fipá báàyàn lòpọ̀

Idajọ iku fawọn afipabanilopọ

Oríṣun àwòrán, AFP

Iku lere ẹṣẹ bayii fun ẹnikẹni to ba fipa baayan lopọ ni ipinlẹ Jigawa bayii.

Gomina Muhammad Badaru ipinlẹ Jigawa lo buwọlu ofin idajọ iku fun ẹnikẹni to ba fipa baayan lopọ to si tun ko arun HIV/AIDS ran an bayii.

Koda ẹni ti wọn ba fipa ba lopọ gan yoo gba ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira owo gba mabinu.

Àkọlé fídíò, Ọkọ mi bá àwọn ọmọ wa sọ̀rọ̀ lágo kan kó tó wọ bàálù tó já, àmọ háà! - Ìyàwó Olasunkanmi Olawunmi

Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa lo kọkọ gbe abadofin ọhun lọ siwaju gomina lẹyin ti gbogbo ile ti buwọlu tan an.

Nigba to n buwọlu ofin naa, Gomina Badaru lu adajọ agba to tun jẹ kọmiṣọnna eto idajọ nipinlẹ naa, Musa Aliyu ati igbimọ Ulamas lọgọ ẹnu fun aṣeyọri ofin ọhun.

Gomina ni oun buwọlu ofin naa lẹyin tawọn igbimọ Ulamas fi da oun loju pe ofin naa ko tako ofin Islam ati aṣa awọn eeyan ipinlẹ Jigawa.

Ofin Sharia ni yoo bori ti o ba da bi ẹni pe ofin tuntun yii fẹ tako ofin ẹsin Islam.

Ẹwẹ, alaga igbimọ Ulamas, Bashir-Ahmad ṣalaye pe awọn ṣe agbeyẹwo ofin tuntun naa, o si wa ni ibamu pẹlu ofin ẹsin islam.

Ọkunrin naa gbe oriyin fun gomina fun igbagbọ to ni ninu igbimọ Ulamas lati ṣiṣẹ lori ofin naa.

Ofin tuntun ọhun tun sọ pe idajọ ẹwọn gbere ni yoo maa wa fun ẹnikẹni to ba da kẹmika bi ''acid'' si ara ẹni ti wọn ba fipa ba lopọ lara.