Faiza Autism Girl, Ọmọ ọdun 21 tí kò sọ̀rọ̀, ó ń tọ̀, yàgbẹ́ sára, mi ò sì lè gba ẹ̀mí rẹ̀ - Aderonke Olatunji
Iya ọmọ to ni ipenija ti wọn n pe ni ẹya "Autisim" ni ọpọ eniyan lo ti gba oun nimọran lati pa ọmọ naa ko le maa gbe igbe aye tirẹ lọ.
"Aimoye eeyan lo ti pe mi pe, oo le maa ba igbesi aye ẹ lọ bayii, o ma ṣi ma lọkọ mii..., o jẹ yaa wa nkan ṣe sọ̀rọ̀ ọmọ yii koo jẹ ko lọ sinmi".
Amọ, abiyamọ o ku ọrọ ọmọ lero ati ọrọ ti yoo kọkọ tu jade bi eeyan ba ri iya ti iya Faisal n jẹ lati moju to ilera ọmọbinrin rẹ to ni ipenija ara yii ti awọn oloyinbo n pe ni "Asperger's syndrome" tabi ẹya eyi to wọpọ ti ẹ mọ si "Autism".
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ fun BBC Yoruba to ṣe abẹwo si iya ati ọmọ ọhun, ọpọlọpọ ilana ibilẹ ni wọn ti gba lati tọju rẹ ki awọn dokita to ri nkan to n ṣe e gangan.
"Ti mo ba mu ọmọ yẹn jade, awọn eeyan a maa wo mi bi iran tori ẹ o ti ri i lara ẹ pe nkan n ṣe e".
- Ọkọ mi bá àwọn ọmọ wa sọ̀rọ̀ lágo kan kó tó wọ bàálù tó já, àmọ háà! - Ìyàwó Olasunkanmi Olawunmi
- Glaucoma lè fọ́ gbogbo ènìyàn lójú tán níbí - Dókìtà Nàìjírìà
- Sir Shina Peters ní ẹ ṣé, ìjà ti parí lórí ọ̀rọ̀ tó kan ọmọ olóògbé Funmi Martins; Damilare rẹ́rìín músẹ́ láì sọ̀rọ̀
- Wo àwọn ìlú tó jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ àti èèwọ̀ ni láti kú níbẹ̀
Iya Faisal Akankemi ko lee sọ gbogbo nkan toju wọn ti ri nipa itọju ọmọ na.
Ṣe ti ko maa dede fọwọ kan ero inu ọkọ titi wọn yoo fi sa bọ silẹ ni abi.
Ipele ipele ni iṣoro naa wọle si i lara. "O jokoo titi to fi pe ọdun meji ni ko dide rara, igba to ya, ao tun gbọ ohun kankan lẹnu fun ọdun bii meji mẹta to fi rin".
Ọrun ko duro, a maa yagbẹ sara...
- Mo ṣèlèrí láti ṣa ipá mi fún ìpínlẹ̀ Ondo ní sáà kejì - Rotimi Akeredolu
- Àwà "boys" àdùgbó là ń fara kó iná, gbogbo àwọn panápáná Akure ló sá padà - Ará àdúgbò
- Àdó olóró ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí sekú pa èèyàn mẹ́wàá ní Maiduguri, ọ̀pọ̀ farapa yána yàna
- Ó ti tó ọdún mẹ́fà, méje tí mo ti rí Àùntí Mide Funmi Martins gbẹ̀yìn, wọ́n tún ṣẹ̀ ń ṣèlérí - Damilare
Gbogbo eyi ni iya ro papọ ti wọn fi gbe e lọ fun ayẹwo ọpọlọ. Airi owo ogun ra gẹgẹ bi awọn dokita ṣe ni ki wọn maa ṣe gan lo maa n fa iṣoro ju ti gbogbo adugbo a maa binu tori ariwo rẹ.
Iṣẹlẹ yii ti sọ iya Faizal di ẹni to n tọrọ owo ko to jẹun.

