Plane crash in Abuja: Bàbá ṣì wà, ìyá wà, ìyàwó àtàwọn ọmọ ló kúnlẹ̀ yìí

Àkọlé fídíò, Ọkọ mi bá àwọn ọmọ wa sọ̀rọ̀ lágo kan kó tó wọ bàálù tó já, àmọ háà! - Ìyàwó Olasunkanmi Olawunmi

Iya to bi Olasunkanmi kẹnu bọ ọrọ toun ti omije loju. Ko si ẹni le rẹ ara wọn lẹkun ninu ile tori ati iyawo atiya, ati baba, ẹgbọn aburo to fi mọ awọn ọmọ lo n jẹ ọla pe Olasunkanmi n ṣiṣẹ nileeṣẹ ologun Naijiria.

"Olootọ ti ẹ o le gbe ẹjọ ẹlẹjọ wa ba ni Olasukanmi, ọkọ mi o fawọn ọmọ ẹ ṣere, ko fi emi gan funra mi ṣere".

Omolola Olasunkanmi to jẹ aya ọkan lara awọn ọmọ ologun to ba ijamba baalu to ja ni ẹba papakọ ofurufu Abuja bara jẹ gidi gan nigba ti BBC Yoruba ba wọn lalejo.

Ẹbi Olasunkanmi
Awọn ọmọ Olasunkanmi

Oríṣun àwòrán, NAF

Iyawo rẹ ni aaro rẹ kan n ṣe awọn ọmọ ni wọn dẹ ni ki awọn pe e lori foonu.

Ololufẹ mi, A ti fẹ gbera, baalu wa ti fẹ gbera, o ti fẹ gbera, o daa, ẹ o gunlẹ layọ o".

Iyawo Olasunkanmi

Omolola ni ọrọ ti oun gbọ kẹyin lẹnu ọkọ ohun niyẹn lẹyin ti awọn de lati ṣọọṣi lọjọ naa ti iku mu u lọ.

"Olasunkanmi lo n gbọ gbogbo bukata, temi ni ki n ṣa a ti tọju awọn ọmọ, ko si iṣẹ kankan ti mo n ṣe".

Kii ṣe aya nikan ni Olasunkanmi fi silẹ lọ, ọmọ ọdun mẹsan, mẹfa koda ọmọ ọdun kan ṣoṣo wa lara wọn.

Aburo Olasunkanmi

Oríṣun àwòrán, NAF

[Iy'a Olasunkanmi Olawunmi

Iya Olasunkanmi ṣi wa laye, oun naa bara jẹ. Iyawo ni igba ti ko ba ti si ẹni ti yoo sanwo ile ti wọn n gbe nibo ni ki oun ti bẹrẹ.

Iyawo ni titi de owo "Pampers ọmọ ni Olasunkanmi n fi ranṣẹ. Tori naa, iku rẹ ṣi alafo silẹ gidi gan.

Aworan Olasunkanmi ati Iyawo rẹ
Isinku olasunkami

Oríṣun àwòrán, NAF