Ibarapa Fulani herdsmen attack: Ìdí gaan tí àwọn ìlú Ibarapa ṣe yarí pé àwọn ò fẹ́ Fulani nílùú mọ́ rèé

Àkọlé fídíò, Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé ìròyìn Kayeefi akọnilẹ́nu hààà ṣẹlẹ̀ ní Ibarapa méjèèjè nígbà ìkọlù Fulani?

Niluu ti wọn ti n gbe pọ̀ ni irẹpọ,

niluu ti wọn maa n sọrọ ni tubi nnubi,

nilu ti Yoruba ti n fọmọ fun ọkọ Fulani,

ti wọn si n ṣe wọlẹ wọde...

Ibarapa

Afi biri to yi, ti iroyin n jade pe ikọlu n waye lọtun losi ni ilu Ibarapa. Awn ti wọn finu tan bẹrẹ si ni da wọn wọn si n tẹ wọn loju mọlẹ kọja ifarada to bẹẹ ti awọn ara ilu ni ki gbogbo Fulani kuro ni ilu fawọn.

Ibẹwo BBC si ilu Ibarapa lo wu ọpọlọpọ to farasin lasiko gbogbo laasigbo to waye ni Ibarapa, ipinlẹ Ogun sita.

Èyi kọja afẹnusọ to fi mu ki eto Kayeefi BBC Yoruba yan ibẹ lati wu awọn aṣiri ohun to ṣẹlẹ sita.