Ayinla Omowura: Bí ikú Ayinla Omowura ṣe mi gbogbo ìlú àti ìjọba tìtì rèé látẹnu àwọn ọmọ

Àkọlé fídíò, Gbogbo àwọn Barrister, Kolington tó jẹ́ kòríkòsùn Ayinla Ọmowura, kò sí èyí táa rí nínú wọn' - Haruna, ọmọ Ayinla

Igi nla ni Ayinla Omowura lagbo awọn olorin Yoruba koda bi wọn da gbogbo olorin Naijiria pọ, Ayinla jẹ ọkan gboogi lara wọn.

Lai takurọsọ, Ayinla Omowura jẹ ọkan lara awọn ojulowo olorin ọmọ Yoruba lati igba ti orilẹede Naijiria ti gba ominira lọwọ awọn oyinbo amunisin.

Ẹwẹ, iku rẹ kii ṣe ohun ti eeyan maa n fẹ diju lati sọ toripe iroyin rẹ ba ni lọkan jẹ pupọ lo rọ mọ iku rẹ.

Awọn ọmọ ollogbe naa gba BBC Yoruba lalejo ni ile wọn nilu Abeokuta nibi ti wọn ti ṣalaye bi iku baba wọn ṣe gba gbogbo ilu kan ati ohun ti oju wọn ri lẹyin iku baba wọn.

"Ileewe ni a wa ti a ti dede gbọ iroyin pe gbogbo igboro daru ti wọn si kede konileogbele nitori wipe Ayinla Omowura papode".

Haruna Ayinla Omowura to jẹ ọmọ bibi inu Oloogbe, lo sọ eyi fun BBC Yoruba. O ni wọn sọ̀ fun oun ipe igo ni wọn ti gba oloogbe lori nigba ti wọn yoo si fi dele, baba ti ku.

O ti to ogoji ọdun gbako sẹyin bayii ti Ayinla Omowura ku ṣugbọn ti ohun rẹ ṣi n kan tantan leti awọn eeyan nipa ẹbun orin ti Ọlọrun tun fun ọkan lara awọn ọmọ rẹ.

Eyi lo fun Haruna Ayinla Omowura ni igboye lati sọ pe awọn to n kọ Fuji ti wọn ni Fuji ni Oba orin pe kii ṣe Apala, ko ni oye rẹ to tori Fuji naa ni wọn lee kọ wọn o le ri Apala kọ rara.