Fuji Music: Kollington Ayinla sọ ẹni tó dá orin Fuji sílẹ̀ gan an ní Nàiìjíríà
Agbaọjẹ olorin Fuji ni Naijiria, Alhaji Kollington Ayinla tun ti yanna na bi orin Fuji ṣe bẹrẹ lorilẹede Naijiria.
Ọpọ awuyewuye lo ti wa lori ẹni ti o bẹrẹ orin Fuji ni Naijira laarin oloogbe Sikiru Ayinde barrister ati Alhaji Kollington, Kebe n Kwara.
Amọ, Kollington fun ra rẹ naa ti fi kọ orin pe ''Edumare fiṣẹ yin wa gbogbo wa, lagbaja lo da Fuji silẹ, ọrọ awawi, tamẹdo lo da Fuji silẹ, Edumare fiṣẹ yin wa gbogbo wa.''
- Kí ló tún ṣe Òṣèré fíìmù Yorùbá míì tó ń gba ẹ̀jẹ̀ àtomi níléèwòsàn?
- Jide Kosoko forin sẹ́nu sọ pé òun ni igi lẹ́yìn ọgbà Mr Latin lórí ipò ààrẹ TAMPAN tó wà
- Igbo Olodumare rèé, níbi tí Ìgbín ti tóbi ju Ìjàpá lọ
- Wo àwọn Adelé-Ọba aládé méje tó jẹ́ obìnrin nílẹ̀ Yorùbá
- Kí ló fà ogun Ìjàyè àti ìṣubú Kurunmi, ìfẹ́ ìlú ni àbí orí kunkun?
- Ọkọ mi kìí bọ òkun, "Elder" ni ní ṣọ́ọ̀ṣì àmọ́ ìdí nìyí tó fi bọ̀wọ̀ fún ìpè mi - Olokun Omolara
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu ileeṣẹ FUJI: A Opera, Kollington gba pe oloogbe Ayinde Barrister lo da ere Fuji silẹ nigba ti oun tẹ le e ninu iṣẹ orin Fuji.
Nibi akanṣe eto naa to waye ni Alliance Francaise de Lagos/The Mike Adenuga Center, Ikoyi, Kollington sọ pe orin Fuji ti kọja bẹẹ lasiko yii.
Kollington ṣalaye pe oun ko lero pe orin Fuji le di gbajugbaja orin bi o ti da lonii.
''Orin gidi ni orin Fuji, o ti kan kaakiri gbogbo agbaaye bayii, gbogbo eeyan ni Naijiria lo fẹ kọ orin Fuji bayii,'' Kollington lo sọ bẹẹ.
Alhaji Kollington fikun ọrọ rẹ pe ijinlẹ ede Yoruba lawọn maa n fi kọ orin Fuji ṣugbọn laye ode oni ''awọn ọmọ wa ti fi ede oyinbo si orin Fuji lati le jẹ ko jẹ itẹwọgba sii kaakiri agbaaye.
- Kollington Ayinla ti sọ ẹni tó dá orin Fuji sílẹ̀ gan an ní Nàiìjíríà
- Ìjọba gbé ilé ijó oníhòhò tì pa lórí ẹ̀sùn títàpá sí ìlànà àti dẹ́kun coronavirus
- Wo àwọn Adelé-Ọba aládé méje tó jẹ́ obìnrin nílẹ̀ Yorùbá
- Mi ò le tòṣì láéláé! Ẹni tó bá ń bínú kàn ń bínú lásán ni- Oyedepo
- Wo àwọn ohun tí Amotekun kò ní le è ṣe mọ́ ní ìpínlẹ̀ Oyo...





