Ede Poly Rector suspension: Wọ́n ní kí ọ̀gá àgbà Pólì Ede lọ rọ́kún ńlé lórí ẹ̀sùn pé 'ó kan bẹ́ẹ̀dì sí ọ́fíìsì'

John Adekolawole

Oríṣun àwòrán, Facebook/John Adekolawole

Igbimọ alaṣẹ ile iwe giga Poli Ede ni ipinlẹ Osun ti ni ki ọga agba ileewe naa, John Adekolawole lọ rọkunle.

Agbẹnusọ ile iwe naa, Sola Lawal sọ fawọn akọroyin pe lootọọ ni wọn ti sọ pe ki ọga agba ile iwe lọ rọkunle.

Amọ Ọgbẹni Lawal kọ lati ṣalaye ohun to fa a ti igbimọ alaṣẹ ile iwe naa fi sọ fun Adekolawole lọ rọkun nile.

Agbẹnusọ ile iwe giga naa ṣalaye pe alaga ẹgbẹ awọn olukọ ASUP nile ẹkọ naa, Ọgbẹni Adekunle Masopa ti fi igbesẹ igbimọ alaṣẹ to awọn olukọ ileewe ọhun leti

Ọgbẹni Masopa alaga igbimọ alaṣẹ sọ idi mọkanlelogun tawọn fi ni ki ọga agba ileewe naa lọ rọkun nile.

Lara ẹsun ti wọn fi kan ọgbẹni Adekolawole ni pe o fi iṣẹ rẹ silẹ lai ṣe fun odidi oṣu kan.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa: Mọ̀ síi nípa ìró afárànma àti agbárànmọ́ fáwẹ́ẹ̀lì Yorùbá

Bakan naa ni wọn tun fi ẹsun iwa ibajẹ lọfiisi kan Adekolawole pe niṣe lo lọ gbe bẹẹdi nla sinu ọfiisi rẹ eyi ti yoo jẹ ko maa sun lẹnu iṣẹ.

Ṣugbọn ohun ti agbẹnusọ ile iwe naa sọ ni pe oun gbọ pe igbimọ alaṣẹ ni ki ọga agba ileewe naa yẹba fun ọfiisi amọ oun ko ri iwe apilẹkọ to fidi rẹ mulẹ.

Amọ, Ọgbẹni Lawal ni ko si ewu kankan lori ọrọ naa, o ni gbogbo rẹ ni yoo ni iyanju laipẹ.

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Wo ìtàn ìyá kan ìyá kan àtàwọn olè ajọ́mọgbé tó n ta ọmọ ní Kenya