New Covid 19 update: Ẹ̀yà kòkòrò Covid-19 míràn jáde ní ọgọ́ta agbègbè nílẹ̀ Gẹẹsi, àjọ elétò ìlera fọkàn ará ìlú balẹ̀

Covid 19

Oríṣun àwòrán, @NCDC

Ẹyà kòkòrò Covid-19 míràn yọjú ní ọgọta agbègbè nílẹ́ Gẹẹsi, àwọn eleto ìlera ni k'ara ilu má fòyà.

Akọwe ilera lorileede Gẹẹsi Matt Hancock ti sọ fún àwọn aṣofin ile naa pe awọn ti ṣawari irufẹ ẹyà kokoro àrùn Covid-19 mi ti a máa yara tan ka.

Matt Hancock salaye pe o kere tan ọgọta agbegbe ni wọn ti ri akọsilẹ itankalẹ arun Covid-19 tuntun yi.

Matt ni awon ti fi to ajọ ilera agbaye leti ati pe ilese ayẹwo ilera ile naa Porton Down ti n se Iwadii nipa rẹ.

Ọgbẹni Hancock ni "awọn ko ri aridaju pe o n fa arun yi lagbara ju èyí to wa nilẹ lọ tabi pe abẹrẹ ajẹsara ko ni ṣiṣe mo."

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa: Mọ̀ síi nípa ìró afárànma àti agbárànmọ́ fáwẹ́ẹ̀lì Yorùbá

Bẹẹ lo sàlàyé fún àwọn aṣofin ile ilẹ naa pe nise lawọn ṣakiyesi alekun iye àwọn to ni arun naa kaakiri London, Kent, apa kan agbegbe Essex ati Hertfordshire.

"A ko mọ bi ẹda kokoro yi se lagbara sí sugbon a gbodo gbe gbogbo igbesẹ tó yẹ ní kíákíá lati dẹkun rẹ pẹlu bi a ti ṣe n fun awọn eeyan labẹrẹ ajẹsara"

Àkọlé fídíò, Kollington ṣàlàyé bí orin Fuji ṣe bẹ̀rẹ̀ gan an ní Nàiìjíríà

Ọjọgbọn Alan McNally, to jẹ akọṣẹmọṣẹ ni fasiti Birmingham, ni laarin ọsẹ bi meloo to kọja lawọn laabu ilẹ Gẹẹsi kẹfin kokoro tuntun yi.

" A ti n gbé igbesẹ lati mọ bi ẹyà kokoro tuntun yi ti ṣe waye.

O ṣe pataki ki gbogbo eeyan fi ọkan woye ẹyà kokoro tuntun yi nitori kokoro a máa yira pada lóòrèkóòrè ti o sí ṣeeṣe ki kokoro yi máa lọ ki sí maa bọ to ba ya"

Àkọlé fídíò, Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni wọ́n ti já àbálé Esra lábẹ́ àwáwí àyẹ̀wò wúndíá