Covid-19 second wave: ''Ìjọba kò tíì pàṣẹ ìlànà ìtakété-síra-ẹni padà nínú BRT la ò ṣe tíì ma tẹ̀le''

Oríṣun àwòrán, Facebook/LBLS
Kaka ki ewe agbọn dẹ, niṣe lo n le koko sii. Bẹẹ lọrọ ṣe ri pẹlu ajakalẹ coronavirus ẹlẹẹkeji to n kan ilẹkun bayii lorilẹede Naijiria papaa julọ nipinlẹ Eko.
Gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun ni Naijiria, NCDC, eeyan to din ọgọrin ni ẹgbẹrun mẹrun(3,820) lo ko arun coronavirus lapapọ ni Naijiria lọsẹ to kọja.
Koda Gomina Babajide Sanwo-Olu ipinlẹ Eko naa wa lara awọn eeyan ọhun.
- Èyí ni bí gómìnà Babajide SanwoOlu ti ìpínlẹ̀ Eko ṣe kó COVID-19
- Wo àwọn Ọba aládé méje tó jẹ́ obìnrin nílẹ̀ Yorùbá
- Kí làwọn nǹkan tó lè rán ọkùnrin sí ọ̀run alákeji lásìkò ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin?
- Wo àwọn oúnjẹ márùn ún tó ń mú kí àtọ̀ ọkùnrin dára síi
- Wo àwọn ohun tí Amotekun kò ní le è ṣe mọ́ ní ìpínlẹ̀ Oyo...
- Àṣeyọrí Anthony Joshua fi hàn pé owó tí à ń ná lórí eré ìdarayá kò lọ lásán - Dapo Abiodun
Ajọ NCDC sọ pe igba akọkọ ree tawọn to larun naa yoo pọ to bayii ni nkan bi oṣu mẹrin sẹyin.
Awọn oṣiṣẹ eleto ilera si ti sọ pe ami leyi jẹ pe ajakalẹ arun covid-19 ẹlẹẹkeji n kan ilẹkun gbọngbọn papaa nipinlẹ Eko.
Ṣugbọn akiyesi wa ni pe awọn ọkọ akero to fi mọ ọkọ akero ijọba BRT ko tẹle ilana itakete sira ẹni ti ajọ NCDC la kalẹ mọ.
Niṣe ni gbogbo ọkọ naa n kun fọfọ lai si aga ijoko kan to ṣofo.

Oríṣun àwòrán, Facebook/LBSL
BBC Yoruba kan si ọga agba ileeṣẹ ọkọ akero BRT ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Idowu Oguntona lori ọrọ yii.
Ọgbẹni Oguntona gba pe lootọọ ni awọn ko tẹle ilana itakete sira ẹni mọ ninu awọn ọkọ ero BRT nitori ijọba ipinlẹ Eko ko tii paṣẹ pe ki awọn maa ṣe bẹẹ ni.
Ọga ọkọ BRT ni awọn si n ri wi pe awọn ero wọ ibomu wọn, lo sanitisa sọwọ, bakan naa lawọn n yẹ ara wọn wo bo ya o gbona tabi ko gbona lati le mọ bo ya wọn ni covid-19.
O fikun ọrọ rẹ pe awọn ko gba kawọn ero maa duro ninu awọn ọkọ naa mọ, wọn kan n joko lasan an ni.
Ọgbẹni ṣalaye pe ijọba Eko naa ti n wo ṣaakun ọwọja covid-19 lẹẹkeji lati mọ iru ilana ti wọn tun fẹ gbe kalẹ.
Amọ, ọga agba ọkọ ero BRT ipinlẹ Eko ko ṣai ṣalaye pe ijọba ni lati roo daadaa ki wọn to gbe ilana mii kalẹ nitori akoba ti coronavirus ti ṣe fun ọrọ aje tẹlẹ.
- Wo àwọn Adelé-Ọba aládé méje tó jẹ́ obìnrin nílẹ̀ Yorùbá
- Èyí ni àwọn aṣíwájú ìjọba tí ajé ìwà ìjẹkújẹ ti ṣí mọ́ lórí láàrin ọdún 1960 sí àsìkò yí
- Mi ò le tòṣì láéláé! Ẹni tó bá ń bínú kàn ń bínú lásán ni- Oyedepo
- Lóòtọ́ ni mo yìnbọn níbi yánpọnyánrin tó wáyé ládúgbò mi-Seun Kuti
- Wo àwọn ohun tí Amotekun kò ní le è ṣe mọ́ ní ìpínlẹ̀ Oyo...














