Coronavirus in Nigeria: Amúgbálẹ́gbẹ́ Gómìnà SanwoOlu kó àrùn COVID-19 ràn án, àmọ́ wọ́n ní àrùn náà kò dá a wólẹ̀

Oríṣun àwòrán, Twitter/babajide sanwoOlu
Ni ọjọ Abamẹta ni iroyin gbode pe gomina ipinlẹ Eko, Babajide SanwoOlu ti ko arun COVID-19.
Kọmiṣọna feto ilera ni ipinlẹ naa, Ọjọgbọn Akin Abayọmi lo kede rẹ lẹyin ti wọn ti kọkọ kede lọjọ Ẹti pe yoo lọ yara rẹ sọtọ titi ti igba ti esi ayẹwo kan to ṣe yoo jade.
Gomina SanwoOlu ni lati ṣe ayẹwo naa nitori iroyin fihan pe ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ rẹ kan ti kọkọ ko arun naa laarin ọsẹ ọhun.
Amọṣa kọmiṣọna feto ilera, Akin Abayọmi ni COVID-19 to ṣe gomina naa kii ṣe eyi tii da ni wolẹ nitori awsn afihan kekeke lo n fi han lara gomina naa.
O fi kun un pe ikọ ilera lati ile iwosan ajakalẹ arun, IDH to wa lagbegbe Yaba ti bẹrẹ eto itọju fun gomina naa.
Sanwo-Olu, El-Rufai fara pamọ́ torí COVID-19 lẹ́ẹ̀kejì

Oríṣun àwòrán, Silverbirdtv
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti yẹra fawọn eeyan fun igba diẹ naa.
Eyi ko ṣẹyin bi amugbalẹgbẹ rẹ kan ṣe ko arun COVID-19 laipẹ yii.
Kọmiṣọna feto ilera ni ipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayọmi salaye pe igba mẹta ọtọọtọ ni wọn ti ṣe ayẹwo fun gomina Sanwo-Olu ṣugbọn piri bayii lolongo rẹ n ta.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn agbófinró Nàíjíríà yóò rojọ́ níwájú iléẹjọ́ àgbáyé ICC
- Wo ìgbéyàwó olówó iyebíye tí awakọ̀ Kabúkabú ti jẹ̀bùn ọkọ N3.4m
- Kí ni abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò Anthony Joshua fi n wu àwọn ọmọ Naijiria tí gbogbo wọn fẹ́ tan mọ́ ọ?
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo kéde òfin konile-o-gbele ní Ode ati Ishinigbo lẹ̀yìn rògbòdìyàn tó wáyé níbẹ̀
- Wọ́n ti rí Ọ̀pá Àṣẹ ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun tí àwọn jàndùkú jí gbé nípinlẹ̀ Eko o!
- Wo àwọn tó ti dákú bíi Maina níwájú ìjẹ́jọ́
O fi kun un pe, ayẹwo miran yoo waye fun gomina naa lọjọ Abamẹta lati mọ boya o ti ko arun naa abi bẹẹkọ.
Ẹwẹ, nipinlẹ Kaduna, Gomina El-Rufai naa ti wọ yara iyasọtọ lọ bayii pẹlu bi o ṣe ni awọn kan ninu mọlẹbi, alabaṣiṣẹ ati amugbalẹgbẹ oun, ti ko arun naa.
El-Rufai, to ṣalaye ninu ọrọ kan to ba awọn eeyan ipinlẹ naa sọ ni yiyẹra oun jẹ ara ọna igi gogoro maa gun mi loju, atokere laa tii woo, ti oun n gbe lati fi dena itankalẹ arun naa, aibaamọ bi oun pẹlu ba ti koo.
O ni oun yoo ṣi maa yẹra fun awọn eeyan titi di igba ti esi ayẹwo lati mọ boya oun ni, eyi ti yoo waye lọjọ Aiku, ba ti waye.
Ni oṣu kẹta ọdun yii ni Gomina El-Rufai ti kọkọ lugbadi aarun naa.













