Anthony Joshua: Kí ni abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò Anthony Joshua fi n wu àwọn ọmọ Naijiria tí gbogbo wọn fẹ́ tan mọ́ ọ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ibẹrẹ Anthony Joshua
Wọn mọ ẹbi Joshua daadaa ni ilu Sagamu, ti wọn si mọ itan awọn baba nla rẹ daadaa.
Baba-baba-baba rẹ ni Daniel Adebambo Joshua, ọlọrọ onilẹ ati oniṣowo ti wọn gbagbọ pe o yan orukọ kẹta rẹ nigba to di ọmọlẹyin Kristi.
Daniel ran ọmọ rẹ kan nileewe nilẹ Britain, nibẹ lo ti fẹ obinrin Irish kan to ba a wale pada si Naijiria nibi ti wọn ti tọ ọmọ meje.
Ọkan lara awọn meje ọhun ni Robert to fẹ Yeta Odusanya lati ilu Sagamu kan naa, ohun si ni baba Anthony ati aburo rẹ, Janet.
Orukọ mii ti Anthony n jẹ ni Olaseni.
Awọn aṣeyọri rẹ ninu jija ẹṣẹ fihan pe idile rẹ gbajumọ tayọ ilu wọn nikan de gbogbo orilẹede Naijiria.
Pẹlu iyi lo fi maa n pọn orilẹede rẹ le nibikibi to ba wa, asia Naijiria ko le ma fẹ lẹlẹ nibi to ba ti n ja, koda aworan Afirika wa gbagada lapa rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O maa n fihan pe oun fẹran awọn ounjẹ ibilẹ Naijiria gan
Bi o ṣe fẹran Naijiria to, o ko ounjẹ ranṣẹ sile fun awọn idile ti Coronavirus ṣakoba fun.
O jẹ ẹni to lẹkọ ile pẹlu ọrọ pẹlẹ lẹnu ati ẹrin musẹ to maa n di ẹrin keekee.
O nira ki Anthony ma bori to ba ja ẹṣẹ tori naa irawọ to tan jade wa lati Naijiria ni ọpọ ka a si, eyii si mu ki ọpọlọpọ ololufẹ rẹ lati Naijiria fẹran rẹ gan.
- Ọmọ Naijiria hú ẹ̀sùn ìfipá bánilòpọ̀ tí wọ́n fi kan Fatoyinbo síta lẹ́yìn tó lọ sí Shiloh
- Ìwọ́de ńlá yóò bẹ́rẹ̀ lọ́jọ́ táwọn gómìnà bá yá ₦17trn nínú owó ìfẹ̀yìntì òṣìṣẹ́ - NLC
- Ìdí rèé tí mo fi yan ikọ̀ PMS rọ́pò NURTW nípìnlẹ̀ Oyo - Seyi Makinde
- "Buhari, Olóṣèlú àtàwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run ló mú àjẹbánu gogò ní Nàíjíríà"
Ero maa n wọ ni nibi iworan ti wọn ti maa n wo ija Anthony Joshua ni Sagamu, koda Joshua tun ni ẹgbẹ awọn alatilẹyi n tirẹ ni Sagamu.
O to ẹgbẹrun mẹwa ololufẹ rẹ to wo ija kan, koda awọn kan rinrinajo lọ wo o.
Bi Joshua ko tilẹ ṣe raye ri ipade ṣe pẹlu awọn ololufẹ rẹ nigba to wale ninu oṣu keji, ko sẹni to binu si i, ṣugbọn o ri ọba ati awọn ijoye ko to pada.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Ko si iyọnu, ọmọ wa naa ṣi ni, aṣoju wa si ni," ọkan lara wọn, Okunore lo sọ bẹẹ.
"Mo mọ pe o tan mọ Watford amọ ọmọ ilu wa ni baba ati baba baba rẹ ati babaa babaa babaa rẹ".
Iwuri ni Joshua
Ọpọ ọdọ ni ẹkun Guusu-Ila Oorun lo ti n fi Joshua ṣe awokọṣe pẹlu bi wọn ṣe n wo o ti wọn si n farabalẹ kọ bo ṣe n goke.
Ẹni ọdun mọkanlelogun kan, 'Lekan the Engine' Muibi to jẹ mọkaliiki ni Ooṣa ni Joshua jẹ si oun.
"Mike Tyson gangan lo mu mi fẹran jija ẹṣẹ amọ Joshua lo n ti mi soke pe mo lee moke tori ọmọ Naijiria bii emi loun".












