Seyi Makinde: PMS kò ní ohun ṣe pẹ̀lú NURTW, ìṣẹ́ rẹ̀ ni láti pawó wọlé fún ìjọba

Oríṣun àwòrán, Facebook/ The Park management Oyo state
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti sọ pe ọna lati dena wahala ni ẹka igboke-gbodo ọkọ, lo mu ki oun ṣe ayipada ẹgbẹ NURTW.
Ọdun 2019 ni Makinde gbe igbimọ oluṣakoso kan kalẹ, to pe ni Park Management System (PMS).
Igbimọ yii si lo n mojuto awọn ibudokọ ero dipo ẹgbẹ National Union of Road Transport Workers, NURTW, to ti n mojuto fun ọdun to pọ.
- NURTW l‘Abuja yóò kàn sí Makinde láìpẹ́ lórí bó ṣe fòfin dè wá l‘Ọyọ - Ejiogbe
- Òfin ṣì gbẹ́sẹ̀lé Ẹgbẹ́ awakọ̀ èrò NURTW ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́
- Ohun tí o kò mọ̀ nípa Ebila "One Million Boys" àti Ekugbemi, olórí ẹgbẹ́ òkùnkùn méjì tó da ìlú Ibadan rú
- Ta ló leè rò pé ọmọ mẹ̀kúnnù bí èmi leè dé ipò alága NURTW? - MC Oluomo
- Auxiliary korò ojú sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó ń dàlú rú
- A kò yan Auxiliary ni adarí gáréjì, ọjọ́ Ajé lá kéde orúkọ̀ àwọn alákòsóo tuntun - Ìjọba Ọyọ
Jakejado awọn ipinlẹ to wa ni Naijiria ni NUTW ti n ṣiṣẹ ayafi ipinlẹ Oyo nikan ti wọn ti fofin de ẹgbẹ ọlọkọ ero naa.
Fun'ra awọn ọmọ ẹgbẹ naa si lo ma n yan awọn adari wọn amọ Gomina Makinde fi ofin de ẹgbẹ NURTW naa nitori rogbodiyan to n waye ni gbogbo igba nipa yiyan awọn adari rẹ.

Oríṣun àwòrán, Oyo Affairs
Lasiko to n sọrọ lati ẹnu Igbakeji Olori oṣiṣẹ, Ọgbẹni Abdulmojeed Mogbonjubola l'Ọjọbọ, gomina sọ pe, ipinnu oun lati mu idagbasoke ba ẹka naa, lo fa igbesẹ ayipada ti oun gbe.
O ṣalaye pe eyi si ti mu ki ibaṣepọ to dara wa laarin ijọba ipinlẹ Oyo, ati awọn awakọ ero.
Ati pe, o ṣe pataki fun ijọba lati ri i daju pe alaafia ati irẹpọ wa laarin awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ nipinlẹ Oyo, nitori bi iṣẹ wọn ṣe ni ipa lara ọrọ aje.
Kini ojuṣe ikọ PMS nipinlẹ Oyo?
Gbogbo ijọba ibilẹ mẹtalelogun to wa nipinlẹ Oyo ni igbimọ PMS wa.
Yatọ si wọn, gomina tun da igbimọ meji silẹ, ti yoo ma a pari aigbọra ẹni ye to ṣe e ṣe ko waye laarin ijọba ati awọn ọmọ ikọ PMS.
Akọṣẹmọṣẹ kan lo n dari ikọ PMS, lati ri pe wọn n tẹle ilana iṣẹ wọn

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde
Ijọba Oyo sọ pe PMS ko ni ibaṣepọ pẹlu NURTW. Ijọba lo gba awọn ọmọ ikọ PMS si iṣẹ lati di gbogbo ibi ti owo n gba poora, ki wọn si tun ri i daju pe owo to n wọle fun ijọba pọ si.
Wọn tun gbọdọ ri daju pe owo to tọ si ijọba n de apo rẹ, ojuṣe ikọ PMS si tun ni lati ri pe kosi sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ, nipa ṣiṣe amojuto awọn ibudokọ.











