Ìjọba Ọyọ: Igba náírà péré làwọn ọlọ́kadà yóò máa san lójúmọ́ fáwọn adarí ibùdókọ̀ tuntun

Oríṣun àwòrán, @transports_NG
Ijọba ipilẹ Ọyọ ti kede pe oun ti yan awọn alakoso ibudokọ lati maa se akoso awọn ibudokọ to wa lawọn gbogbo ijọba ibilẹ to wa jake jado ipinlẹ naa.
Kọmisana fun isẹ ode, Ọjọgbọn Raphael Afọnja, to sisọ ọrọ yii fawọn akọroyin fikun pe ọjọ aje lawọn yoo kede orukọ awọn alakoso ibudokọ ọhun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bakan naa lo salaye pe yatọ sawọn alakoso ibudokọ, ijọba tun ti yan awọn igbakeji alakoso ibudokọ, akọwe ati akapo.
Afọnja fikun pe ojuse awọn alakoso ibudokọ naa ni lati maa gba owo ita ati sise akoso awọn akọsẹmọsẹ lorukọ ijọba, wọn yoo maa gba igba naira lojumọ lọwọ awọn ọlọkada

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
O wa mẹniba pe ahesọ lasan ni iroyin kan to n ja nilẹ pe ijọba ipinlẹ Ọyọ yan alaga tẹlẹ fẹgbẹ awakọ ero, Mukaila Lamidi, ti gbogbo eeyan mọ si Auxiliary, gẹgẹ bii ọkan lara awọn alakoso ibudokọ.
Saaju lọjọbọ ni ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ọyọ ki kede loju opo Twitter rẹ pe ijọba Ọyọ ti yan Auxiliary gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ ọlọkọ ero.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Kọmisana fun isẹ ode wa tẹnumọ pe, ofin to de ẹgbẹ ọlọkọ ero nipinlẹ Ọyọ si wa nilẹ digbi, ti gbogbo owo tawọn asaaju ẹgbẹ ọlọkọ ero ọhun si n gba ko bofin mu.
"Awọn alakoso ibudokọ tuntun yii ni yoo jẹ asoju ijọba, ti wọn yoo si maa gba owo lorukọ ijọba, bẹẹ ni wọn yoo maa san sapo ijọba lati ipasẹ awọn alamojuto, ti yoo san sapo ijọba.
Afọnja ni eyi yatọ si ohun to maa n waye latẹyinwa, ijọba si ro pe o yẹ ki awọn eeyan kan wa ti yoo lewaju ninu pipa owo wọle fun ijọba, gbogbo awọn alakoso gareji ọkọ ati ti ibudo iwakusa ni yoo maa sanwo fun ijọba.
O wa rọ awọn agbofinro lati ri daju pe wọn ko maa gba owo mọ lọwọ awọn ọlọkada, bẹẹ si ni gbogbo awọn asaaju ẹgbẹ onimọto tijọba ti fofin de ko lẹtọ mọ lati maa gba owo lọwọ awọn awakọ ati ọlọkada.













