Oluwo: Olu ní àwọn ọmọ Iwo kan ti ń bẹ̀ àwọn, àmọ́ ta làwọn mọ̀ ti nínà yóò tún kàn

Oríṣun àwòrán, Oluwo
Ọba Agbaje Abeeb Adetoyese, Olu ti Ile Ogbo, ti kesi gomina Adegboyega Oyetola ti ipinlẹ Ọsun lati tete pasẹ pe ki Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi lọ rọọkun nile na, ko si kuro ninu igbimọ lọbalọba fun igba diẹ.
Ọba alaye naa ni eyi ni yoo kọkọ jẹ ijiya ẹsẹ Oluwo lori bo se na ọba alaye bii tiẹ, Agbowo tilu Ọgbaagba lasiko ipade alaafia to waye lọọfisi igbakeji ọga ọlọpa lẹkun kọkanla nilu Osogbo.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ṣeyi Makinde ṣé ìfilọ́lẹ̀ àwọn olùdarí ìbùdókọ́, ó yan Auxilliary lálaga ìgbìmọ̀
- Aláàfin ìlú Oyo, Ikú Bàbá Yèyé tún bímọ tuntun làǹtì lanti
- Ọdọọdún làwọn ọmọ ònilẹ̀ ń dà wá láàmú ní Soka, kí Sunday Igboho tó gbà wá sílẹ̀ - Àwọn olùgbé Soka
- Inec kéde pé olùdíje gómìnà fẹ́gbẹ́ PDP ní Bayelsa làwọn gbà pé ó yege ìbò
- Ó ṣeéṣe kó má sí ẹ̀ṣọ́ aláàbò Amotekun l‘Eko - Ìjọba Eko
- Ẹgbẹ́ alátakò ló sanwó fáwọn èèyàn kan láti pariwo lé ààrẹ Buhari lori - Iléeṣẹ́ ààrẹ
- Torí ǹkan oṣù, Iléèwé pàṣẹ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin tú síhòhò
Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọọ lori isẹlẹ ọhun, Olu tile Ogbo ni oun wa nibi ipade alaafia naa, nibi ti ọga ọlọpa ti n yanju awọn fun awọn ati Oluwo.

Oríṣun àwòrán, Ọba Dikrulahi Ọlaleke Akinrọpo, Ọlabiran Kẹta.
O fikun pe lootọ lawọn ti pe agbẹjọro awọn, sugbọn awọn n rọ ijọba ipinlẹ Ọsun lati le Oluwo kuro lori oye nitori kii se eeyan ti ori rẹ pe lati di iru ipo to wa mu.
"Awa ọba pọ nibi ipade naa bii Onigẹgẹ ti Igẹgẹ,Onitara ti Feesu, Onimese ati Olupọ ti Olupọnna, to fi mọ Oluwo Oke, ti ọga ọlọpa si n bawa sọrọ, sadede ni Oluwo dide, to si n na Agbowo ti Ọgbaagba."
"O na a gidi gan ni, debi pe ẹjẹ bẹ loju rẹ ni, ile iwosan si ni gbogbo wa sare gbe digbadigba lọ ni Asubiaro, ijọba ko si gbọdọ wo Oluwo niran lori ọrọ yii, wọn gbọdọ ni ko lọ joko sile na.

Oríṣun àwòrán, Oluwo
Ọba Adetoyese ni ko yẹ ki ọba to n dari ilu to tobi to ilu Iwo maa dọti ilu Iwo kaakiri, o si yẹ ko gba ijiya to yẹ lori bo se hu iru iwa bayii niwaju ijọba.
Nigba to n salaye ohun to fa laasigbo naa, Adetoyese ni "Oluwo lo n fọwọ gbaya pe oun loun ni gbogbo ilu wa, oun loun ni Ile Ogbo, Ọgbaagba, Idi Ẹgẹ, Feesu, Ọlọja biire, Onifin, Olupọnna, Iwo Oke ati gbogbo ilẹ, o ni a n ta ilẹ oun, ta si sọ fun pe a ko ta ilẹ rẹ, ilẹ ilu wa la n ta."

Oríṣun àwòrán, Oluwo
O fikun pe, bi Agbowo Ọgbaagba sọ fun pe ilẹ Ọgbaagba ni oun n ta, bi Oluwo se binu dide niyẹn, to si da igbaju-igbamu boo, lai jẹ pe a sọ ọrọ to ju ẹnu wa lọ si.
"Awọn ẹgbẹ ọmọ Iwo kan ti n bẹ wa pe ka ma jẹ ko le fun, amọ ko si bi ko se ni le fun, nitori a ko mọ ẹni ti yoo kan lọla, emi gan lo kọkọ fẹ na, amọ mo jinna sibi to joko si, ni ko jẹ ko na mi."
Ìjà àgbà méjì! Oluwo gbá Ọba Ọ̀gbàágbàá lójú níbí ìpàdé àláfíà, ẹ̀jẹ̀ tọ
Iroyin kan to n tẹ wa lọwọ ni ija nla ti bẹ silẹ laarin awọn ọba alaye meji, eyiun Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi ati Agbowu tilu Ọgbaagba, Ọba Dikrulahi Ọlaleke Akinrọpo, Ọlabiran Kẹta.
Aawọ naa buru to bẹẹ gẹẹ, ti awọn mejeeji tahun sira wọn, eyi to mu ki Oluwo bu igbaju-igbamu lu Agbowu, ti ẹjẹ si n tu jade ni ẹẹkẹ rẹ.
Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, Ọba Akinrọpo salaye pe, ọjọ ti pẹ ti awọn ti n paara ọdọ ọlọpa, lati saa igbakeji ọga ọlọpa fẹkun keji, Oyebade, nitori bi Oluwo se wọ awọn ọba mẹjọ kan lọ siwaju ọga ọlọpa naa.
O ni Oluwo fẹsun kan awọn ọba mẹjẹẹjọ naa, bii ọba Ọgbaagba, Kuta, Ile'gbo pe awọn n dunkooko mọ ẹmi oun, nitori bi awọn se n ta ilẹ ni agbegbe awọn
Akinrọpo ni awọn sọ fun Oluwo pe awọn ko ta ilẹ nilu Iwo bikose agbegbe awọn, ti wọn si pe ipade alaafia laarin awọn lati yanju aawọ naa, amọ o ni n se ni Oluwo n da ipade naa ru.
"Se ni Oluwo n da ijoko naa ru lọdun to kọja, ti wọn si tun pe ipade alaafia miran lọdun yii si ẹkun kọkanla ileesẹ ọlọpa nilu Osogbo, iwaju ọga ọlọpaa naa la wa, nibi to ti n rọ wa lati gba alaafia laaye. Ibi ta ti n salaye pe a ko lọ ta ilẹ nilu Iwo, ilẹ ọdọ wa la n ta, ni Oluwo ti sọ pe, ki lo de ti oun n sọrọ, ti emi naa n sọrọ, abi ori mi daru ni."

Oríṣun àwòrán, Oluwo
"BI Oluwo se dide ree, to n lu mi mọlẹ, to ni oun yoo jẹ ki emi mọ pe oun ni ọba ati ọga. Bo se n gba mi loju, gba mi nimu ree, niwaju AIG, Kọmisana fọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, pẹlu Kọmisana fọrọ ilẹ ati ilegbe ati alaga fun ijọba ibilẹ Iwo atawọn ọba miran, to fi mọ Olupọ tilu Olupọnna."
Akinrọpo fikun pe, oun ko sọrọ ibinu rara si Oluwo to fi n na oun, ti ẹjẹ si n da loju oun, koda ọga ọlọpa gan lo n sọrọ lọwọ, to fi dide mọ oun.
"Mo kan sọ fun pe ọba ni olukaluku wa, a si n se akoso agbegbe wa, ki wa lo de ti yoo fi maa pasẹ pe awọn ko gbọdọ ta ilẹ to wa ni agbegbe awọn."
Ọlọgbaagba ni ile iwosan ni oun ti n ba wa sọrọ lati lọ gba itọju, to si pẹ diẹ lẹyin to na oun tan, ki ara oun to balẹ, ti wọn si gbe oun lọ sile iwosan. O ni oun ko mọ ohun to fi gba oun loju, ki ni naa ya oun loju, ti ẹsẹ si n yọ.
O ni awọn ọlọpa ti gba ọrọ silẹ lẹnu awọn nitori oju wọn naa lo ti sẹlẹ, oun si fẹ ki ofin gbe igbesẹ to ba yẹ lori rẹ.
Gbogbo igbiyanju wa lati ba Oluwo sọrọ lori isẹlẹ naa, lo ja si pabo, to si sọ fun wa pe ara oun ko tii bọ sipo lati ba wa sọrọ.
Amọ nigba ta kan si alukoro ileesẹ ọlọpa ipinlẹ Ọsun, Folasade Odoro, o ni awọn ko tii gbọ nipa isẹlẹ naa, yoo si daa ka kan si ẹkun ileesẹ ọlọpa fun alaye.
A mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin laipẹ, ti awọn mejeeji ba ti ba wa sọrọ













