Operation Amotekun: A ó da ọlọ́pàá agbègbè àti Amotekun papọ̀ - Ọ̀gá ọlọ́pàá Naijiria

Oríṣun àwòrán, @ekitistategov
Ọga agba ajọ ọlọpaa orilẹ-ede Naijira, Muhammed Adamu ti sọ pe ọlọpaa agbegbe tí ijọba apapọ n gbero rẹ yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu ikọ Amotekun ilẹ Yoruba.
Adamu lo sọ ọrọ yii nibi ijiroro kan to waye pẹlu awọn gomina ilkẹ Yoruba nilu Eko lori agbekalẹ ọlọpaa agbegbe.
O sọ fun awọn akọroyin pe "Ipade keji niyi ti a maa ṣe pẹlu awọn gomina naa lori agbekalẹ ikọ Amotekun."
- Àwọn ọmọ onílẹ̀ lọ ṣe àmúṣẹ àṣẹ iléẹjọ́ ní Soka, làwọn ‘Jàǹdùkú’ fi dá wọn lọ̀nà - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ọyọ
- Bàbá àti ìyá mi kò fẹ́ kí n ṣe eré tíátà - Wale Akorede Okunnu
- Àwọn ọmọ Naijiria sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ yẹgi mọ́ Olùdíje gómìnà APC ní Bayelsa nídìí
- Káńsélọ̀ Sajid Javid kọ̀wé fipò sílẹ̀ lẹ́yìn tí Boris Johnson ṣàtúntò ìjọba rẹ̀
Adamu ṣalaye pe "Gbogbo ipinlẹ lo ni eto abo ti wọn lati koju iwa ọdaran, ikọ Amotekun ko si yatọ si iru agbekalẹ bẹẹ.
O ni ajọ ọlọpaa ati awọn gomina naa ti fẹnuko lati sọ ọlọpaa agbegeb ati Amotekun di ọkan ṣoṣo ki eto abo ilu lee jẹ lati ọwọ awọn ara ilu.

Oríṣun àwòrán, @followlasg
Ọga agba ajọ ọlọpaa naa tẹsiwaju pe ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria yoo lọwọ si igbanisiṣẹ ati idanilẹkọ awọn eeyan ti yoo ṣeṣẹ gẹgẹ bi ikọ Amotekun.
- Lẹ́yìn ọdún 44 tó jáde láyé, igbá tí onírèsé Murtala Muhammed fín sílẹ̀, kò parun
- Ẹ̀yin òṣèrè tíátà, ẹ ní ṣùúrù de àsìkò Ọlọ́run, ẹ máṣe kánjú kọjá kádàrá - Madam Ṣajẹ
- "Iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lórí rédíò máa ń mú ẹ̀wà àti àpọ́nlé ba ni àmọ́ kò lówó lórí"
- Ìjọba san ₦200,000 fún Sowore, ó sọ fúnlé ẹjọ́ pé òun kò jẹ̀bi ẹ̀ṣùn
Adamu sọ pe eto abo gbọdọ bẹre lati ọdọ awọn ara ilu, lẹyin naa lo rọ awọn eeyan lati fọwọsowọpọ gbogun ti iwa ibajẹ.
Adamu pari ọrọ rẹ pe ajọ ọlọpaa yoo ṣatilẹyin fun awọn eeyan lati ri pe agbegbe wọn wa ni alafia.












