Murtala Mohammed: Aṣaájú tó kọ́kọ́ gbógun tàwọn alájẹbánu, tó sì ta oúnjẹ lọ́pọ̀

Muritala Muhammed

Oríṣun àwòrán, @AgbaAkin_MA

Bi wọn ba darukọ ọgagun Murtala Mohammed letigbọ awọn ọdọ lode oni,ohun ti wọn yoo fi ranti rẹ ni owo beba ogun Naira, eleyi ti wọn ya aworan rẹ si.

Bẹẹ si ni Murtala Mohammed ju ogun Naira lọ, ta ba n sọ nipa ipa to ko lorileede Naijiria ati isẹ iadagbasoke to se fun orilẹede yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi a ba ka ni meni meji, o ti to ọdun mẹrinlelogoji ti akọni ologun yii re irinajo aremabọ, nigba ti awọn agbebọn da ẹmi rẹ legbodo.

Muritala Muhammed ti wọn ya sara ogun naira

Oríṣun àwòrán, @AgbaAkin_MA

Loni ti awọn ọmọ Naijiria si tun n ṣe iranti rẹ, a ni ki a mu awọn ohun to gbe ṣe lasiko to fi wa lori oye fun ọjọ mejidinnigba wa si iranti yin, nitori bi onirese rẹ ko ba fingba mọ, awọn eyi to ti fin silẹ, ko lee parun laelae.

Gẹgẹ ba ti woye rẹ, awọn agbekalẹ ilana isejọba rẹ naa lo si n ṣe atọna awọn ilana isẹjọba laye ijọba alagbada taa wa yii, lai naani pe ijọba ologun ni Murtala Mohammed se adari rẹ nigba naa.

Aworan Murtala Muhammed

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn gudugudu meje, ya ya mẹfa ti Muritala Muhammed ṣe lori oye:

Kikede dukia gẹgẹ bi olori:

Lọdun 2015 lorileede Ghana, nigbati Aarẹ Naijiria Muhammadu Buhari n dahun ibeere awọn akoroyin nipa bi o ti ṣe le jẹ ki awọn olori ilẹ Afrika miran kọ iṣe rẹ nipa kikede dukia.

Buhari fi apẹẹrẹ ọgagun Muritala Muhammed sakawe, to si ni ki gbogbo awọn Minisita ati Gomina to fi mọ awọn akowe agba to siwaju rẹ, kede dukia wọn.

Aworan Murtala Muhammed ati Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Murtala Muhammed ni olori Naijiria akọkọ to fẹsẹ iwa ikede dukia ẹni mulẹ lori aleefa pẹlu bo se kede dukia rẹ setigbọ araye.

Titi di oni, iṣe yii ti di ohun ti awọn eeyan fi n sagbeyẹwo ijọba ti o duro deede ni Naijiria.

Fifi panpẹ ofin mu awọn onijẹgudujẹra:

Orukọ EFCC loni tabi ti ICPC a ma mu ibẹrubojo ba awọn ti wọn ba jẹ ajẹbanu tabi ti wọn ṣe owo ijọba basubasu.

Saaju ki a to ni EFCC ni ọgagun Murtala Muhammed ti paṣẹ ki wọn ṣe iwadi awọn oṣiṣẹ ijọba ti ọwọ wọn ko mọ.

Aworan oluwọde kan nilu Eko

Oríṣun àwòrán, Pius Utomi Ekpe/Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ipenija nla ni ajebanu je fun orileede Naijiria

Bakannna ni Murtala Mohammed ni ki wọn se iwadi nipa awọn dukia ijọba to jẹ alopati lawọn ipinlẹ mẹta kan to wa ni agbegbe ila oorun Naijiria nigba naa.

Yiyọ adajọ agba orilẹede Naijiria:

Awuyewuye ọrọ adajọ agba orileede Naijiria, adajọ Walter Onnoghen ti ijọba Buhari yọ nipo, ko ṣẹṣẹ maa waye ni Naijiria.

Lasiko ti ọgagun Murtala Mohammed fi ṣe ijọba, oun naa yọ adajọ agba orilẹede Naijiria, eyiun adajọ Teslim Elias losu kẹjọ ọdun 1975.

Muritala ati aya rẹ, Ajọkẹ pẹlu awọn ọmọ wọn

Oríṣun àwòrán, @AgbaAkin_MA

Amọ ko pẹ lẹyin igba naa, ti ijọba Murtala Muhammed yii kanna ṣagbega adajọ Elias lọ si ile ẹjọ agbaye taa mọ si International Court of Justice (Hague). O tọ ki a salaye pe yiyọ adajọ Elias ko ni ohunkohun ṣe pẹlu pe o wuwa ajẹbanu.

Ciroma, Olusegun Obasanjo ati Muritala Muhammed

Oríṣun àwòrán, @AgbaAkin_MA

Tita ounjẹ fun ara ilu lowo pọọku:

Lasiko ijọba Murtala Mohammed, awọn ara ilu ri mudunmudun ijọba jẹ paapa julọ, pẹlu pipese ounjẹ bii gaari ati adiẹ lowo pọọku.

Loni ti pupọ ọmọ Naijiria n lọgun ebi, iru igbesẹ ti Murtala Muhammed gbe yii jẹ ọna kan gboogi ti awọn ara ilu n parọwa si ijọba Buhari, lati dẹkun ebi oun iṣẹ to peleke lawujọ.