Insecurity: Àwọn aráàlú ní ìpànìyàn àti ìgbéṣùnmọ̀mí ni kò jẹ́ kí ẹnu sìn lára Buhari

Oríṣun àwòrán, Others
Nkan ko ṣẹnu re fun aarẹ orileede Naijiria lẹnu ọjọ mẹta yii, pẹlu bi awọn ara ilu ṣe n fi ẹhonu han si iṣejọba rẹ.
Yatọ si awọn ti o n bẹnu atẹ lu loju opo ayelujara, awọn ara ilu tun safihan pe inu awọn ko ṣe dun loju koroju pẹlu aarẹ Muhammadu Buhari nipinlẹ Borno.
Lasiko to ṣe abẹwo ibanikẹdun si awọn eeyan Maiduguri, n ṣe ni awọn ara ilu n pariwo pe awọn ko fẹ ẹ mọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho gba àwọn èèyàn Soka n‘Ibadan sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ onílẹ̀ tó wá ṣọṣẹ́
- Ẹ̀yin ọba alayé, ẹ mà ń dákẹ́ pọ̀ lórí ààbò tó mẹ́hẹ ní Nàíjíríà - Sultan figbe ta
- Àgbà olórin, Victor Olaiya jáde láyé.
- Ìpínlẹ̀ Oyo, Ogun, Ondo buwọ́lu àbádòfin Àmọ̀tẹ́kùn
- Ẹ wo àwọn ìlérí tí Buhari ṣe láti ọdún 2015 àmọ́ tí kò tíì mú ṣẹ
Fọnran fidio kan, eleyi to ṣe afihan iṣẹlẹ yii ti gba oju opo Twitter kaakiri, ti awọn ọmọ Naijiria si ti n sọ pe bi aarẹ ko ti ṣe mojuto eto aabo ko jẹ ohun to dun mọ awọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Lẹnu ọjọ mẹta yii, ọwọja ikọlu Boko Haram, paapa julọ ni ipinlẹ Borno, fẹ peleke.
Ni ọjọ Aiku ni ikọ naa dana sun awọn arinrinajo to to ọgbọn, mọ inu ọkọ ni Auno.

Oríṣun àwòrán, @wampa80
Saaju igba naa, wọn ṣe ẹmi awọn ara ilu kanna legbodo ni ilu Gamboru, lẹyin ti wọn yin ado oloro lori afara kan nibẹ.
Awọn iṣẹlẹ yii ati awọn miran to n waye jakejado Naijiria, lo mu ki awọn ara ilu gba oju opo Twitter lati sọ pe, awọn ko fara mọ bi aarẹ Buhari ko ti ṣe mu ọrọ aabo ni koko.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2

End of X post, 3

End of X post, 4
Mo ma gbe igbesẹ lati koju ipenija aabo:
Aarẹ Buhari lasiko abẹwo rẹ ba awọn ara ilu Maiduguri kẹdun, ti o si sọ pe oun yoo tẹramọ igbiyanju lati koju ipenija aabo to n ba wọn.
O rọ awọn olori ilu lati tubọ ma pawọpọ pẹlu awọn ọmọ ogun nipa titawọn lolobo iroyin nipa awọn agbesunmọmi.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5
Aarẹ Buhari ko yọju si ilu Auno ti iṣẹlẹ ikọlu ti Boko Haram ti pa to eeyan ọgbọn ti waye.
Láì lọ́wọ́ ẹ̀yin aráàlú nínú, yóò nira fún Boko Haram láti ṣọṣẹ́ - Buhari sọ fáwọn èèyàn Borno

Oríṣun àwòrán, @SegunAde88
Se ni awọn ilu Maiduguri tii se olu ilu ipinlẹ Borno, tu ya ya jade lọjọru lati pade aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari to se abẹwo sipinlẹ naa.
Amọ yatọ si ijo ati ọyaya tawọn araalu fi saba maa n pade aarẹ to ba wa bawọn lalejo, se ni awọn eeyan yii fi orin abuku pade aarẹ Buhari, ti wọn si n pariwo pe awọn ko fẹ, awọn ko nifẹ si.
Niwọn igba to si jẹ pe ẹni to moju naa ni aarẹ, oun naa ko si sopo bọ awọn ọba alaye to duro lati kii kaabọ lọwọ, ti ko si tun se abẹwo si awọn agbegbe Auno, ti ikọlu ti waye lọjọ Aiku to kọja.

Oríṣun àwòrán, @SegunAde88
Nigba to n salaye idi ti eyi fi ri bẹẹ, Garba Shehu tii se oludamọran agba si aarẹ lori eto iroyin ni "ko si idi fun aarẹ lati lọ si Auno, abẹwo aarẹ si ni lati bawọn eeyan ipinlẹ Borno lapapọ kẹdun nipa ajalu to ba wọn."

Oríṣun àwòrán, @SegunAde88
Nigba to n bawọn eeyan sọrọ lẹnu abẹwo rẹ naa, aarẹ Muhammadu Buhari ni ole kii ja agba, ko ma se loju firi, nitori naa lai si atilẹyin awọn araalu, ko seese fun ẹnikẹni lati wa kọlu agbegbe kankan.

Oríṣun àwòrán, @SegunAde88
"Ẹyin eeyan Borno, bawo lo se rọrun fun ikọ Boko Haram lati maa rọwọ mu di akoko yii lai ni atilẹyin yin ninu? Mo si n rọ yin lati fọwọowọpọ pẹlu awọn agbofinro, ẹ mase gba ikọ Boko Haram laaye lati de ọdọ awọn araalu, mo si n rọ awọn ti wọn le kuro nile wọn lati pada sile.
Buhari ni oun ti setan lati se agbekalẹ awọn ilana to gbopọn lati sẹ eegun ẹyin ikọ Boko Haram, to si tẹnumọ pe sise alabapin iroyin laarin awọn araalu atawọn agbofinro si ni ọna abayọ si aseyọri.