Bishop Kukah: Àkójọpọ̀ àwọn ìlérí tí Buhari mú ṣẹ àti èyí tí kò tíì mú ṣẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bíṣọ́ọ̀bù àgbà ní ìjọ kátólíkí mímọ́, Hassan Kukah ti fi ẹsun kan aarẹ Muhammadu Buhari pe ko mu ileri to ṣe fun awọn ọmọ Naijiria ṣẹ.
Kukah to jẹ olori ijọ katoliki mimọ ni ilu Sokoto sọ ọrọ yii, nitori awọn agbebọn ti wọn pa ọmọlẹyin Kristi, Micheal Nnadi to n kọṣẹ imọ ẹkọ sẹminari, ki wọn to da ẹmi rẹ legbodo.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìsinmi oṣù mẹ́fà lẹ́yìn ìbímọ yóò túbọ̀ mú àdínkù bá ikú mọ wẹ́wẹ́ - Àwọn Obìnrin Ekiti
- Sunday Igboho gba àwọn èèyàn Soka n‘Ibadan sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ onílẹ̀ tó wá ṣọṣẹ́
- Àìsí ẹ̀rọ ìgbàlódé fún bàálù láti bà ní Nàíjíríà, mú káwọn bàálù láti òkè òkun lọ bà sí Ghana
- Ẹ san ₦200,000 fún Sowore lórí bí ẹ ṣe ń fi ẹjọ́ falẹ̀ - Iléẹjọ́ pàṣẹ fún ìjọba
- Buhari, èyí to fí ogún ọdún pilẹ̀ wèrè lórí ètò ààbò Nàìjíríà tó gẹ́ - Bishop Kukah
Eyi lo mu ki BBC Yoruba se akojọpọ awọn ọpọ ileri ti aarẹ Muhammadu Buhari ti se amọ̀ ti ko tii mu sẹ titi di akoko yii.
Lara awọn ileri naa ni lati jẹ ki eto aabo ko gberu si kaakiri orilẹede Naijiria.
Gẹgẹbi ọrọ Biṣọọbu naa, eto aabo lorilẹede Naijiria ti dẹnukọlẹ si ju ti atẹyinwa lọ lasiko iṣejọba aarẹ Muhammadu Buhari.
Amọ kii ṣe ọrọ eto aabo nikan ni aarẹ Buhari ko ti mu ileri rẹ ṣẹ.
Lara awọn ileri ti aarẹ Buhari ti ṣe re e lati ọdun 2015, ti wọn ko si mu ṣẹ re e;
- Aarẹ Buhari kọ lati mu ileri rẹ ṣẹ lori ọrọ rẹ pe oun ko ni lọ si oke okun lati lọ gba iwosan. Aarẹ Buhari fun ara rẹ ti lọ gba iwosan ni oke, ati ọpọlọpọ awọn alabaṣiṣẹ rẹ.
- Aarẹ Buhari kọ lati mu ileri to sọ ṣẹ lori pe oun yoo kede fun awọn araalu, ki wọn le mọ gbogbo owo ati ọla ti oun ni. Amọ Bayii, olubadamọran pataki fun aarẹ Buhari, Femi Adesina sọ wi pe aarẹ Buhari ko sọ nkan to jọ bẹẹ.
- Pabo ni ileri ti aarẹ Muhammadu Buhari ṣe lori eto ina ọba lorilẹede Naijiria. Ko si atunṣe to deba eto ina ọba labẹ iṣejọba aarẹ Buhari.
- Owo ilẹ Naijiria, iyẹn Naira n jo ajorẹyin si ni o,lẹyin ti aarẹ Buhari ṣeleri lati mu agbara ba owo orilẹẹde Naijiria .
- Aarẹ Buhari naa kuna lati mu ileri rẹ ṣẹ lori Ajọ Inec to n bojuto eto idibo ni Naijiria. Ninu idibo ọdun 2019, ajọ INEC sun eto idibo si iwaju lalẹ ọjọ idibo gangan, eleyii ti ọpọ eniyan gbagbọ pe magomago peleke si ninu eto idibo ọdun 2019, labẹ iṣejọba aarẹ Buhari.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
E wo awọn ileri ti aarẹ Buhari ṣe, to si muṣẹ:
- Ipese ounjẹ fun awọn akẹkọọ ni ile iwe alakọbẹrẹ, ti wọn pe orukọ rẹ ni ‘Free School Feeding’.
- Fifun awọn alaini ni miliọnu marun naira lati fi bere idokowo, eleyii ni wọn n pe ni ‘Conditional cash transfer’.
- Pipese iṣẹ fun awọn ọdọ, eleyii ti wọn pe ni N-Power, ti wọn ti n ṣe lọwọlọwọ. Awọn ileri yii ati omiran wa nunu iwe ileri ti ẹgbẹ oṣelu APC, ti ọdun 2015.
- Aarẹ Buhari ti n kọ oke afara 2nd Niger Bridge, ti wọn sọ wi pe awọn yoo pari rẹ ni ọdun 2023. Ileri yii wa ninu iwe ti wọn pe akọle rẹ ni "My Covenant with Nigerians".
- Agbẹnusọ fun aarẹ Buhari, Garba Shehu nigba ti oun fesi si ọrọ ọhun sọ wi pe aarẹ Buhari ko losi iwe to ṣe awọn ileri wọn wọnyii.
- Amọ, iwadii ti ile iṣẹ iroyin Premium Times gbe jade fi lede wi pe aarẹ Buhari ati ẹgbẹ oṣelu APC lo jọ fọwọsowọpọ lati buwolu iwe ọhun.
Buhari, èyí to fí ogún ọdún pilẹ̀ wèrè lórí ètò ààbò Nàìjíríà tó gẹ́ - Bishop Kukah
Loju opo Twitter lorileede Naijiria, orukọ Rev Father Mathew Kukah, to jẹ alagba ijọ Katọliki ẹkun Sokoto Naijira lawọn eeyan n mu bẹnu.

Oríṣun àwòrán, The Guardian Nigeria
Idi to fi jẹ bẹẹ ko sẹyin ọrọ to sọ nibi isin idagbere fun ọmọkunrin to n kẹkọ lati di oniwaasu ijọ Katoliki ti awọn ajinigbe pa ni Kaduna.
Mathew Kukah sọrọ to pọ ninu ọrọ rẹ, eleyi to fi pe akiyesi aarẹ Buhari si ipo ẹlẹgẹ ti eto aabo orileede Naijiria wa.

Oríṣun àwòrán, @paul_terhemba
O ni, o ṣeni laanu pe aarẹ Muhammadu Buhari ko kọbi ara si didaabo bo ẹmi ara ilu, bo tilẹ jẹ wi pe o ṣe ipolongo pe oun yoo koju awọn agbesunmọmi.
Father Kukah ni ijọba aarẹ Buhari jẹ eleyi to kun fun ẹlẹyamẹya ati imọtaraẹnikan, eyi to n mu ipinya wa laarin awọn eeyan Naijiria.

Oríṣun àwòrán, @paul_terhemba
Ninu ọrọ rẹ bakanna o sọ pe aarẹ Buhari ti jẹ ki awọn eeyan ma ni igbagbọ pe, o ṣe pataki lati jẹ Musulumi to wa lati ariwa Naijiria ju ki eeyan jẹ ọmọ ilẹ Naijiria lọ.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Okeygeraldino
O sọ pe nibi ti ọrọ̀ de duro bayi, Naijiria ko mumu laya awọn ọmọ ilẹ rẹ debi pe wọn yoo fẹ fi ẹmi wọn lelẹ fun un.
Kukah ni kaka ki awọn to di ipo mu ni ifarajin fun Naijiria, ipo ti wọn wa, lo wa loke aya wọn.
Kukah wa rọ awọn ọmọlẹyin Kristi lati duro sinsin, ki wọn si mase faye gba inunibini laaye ninu ọkan wọn.
Iku ọmọkunrin akẹkọ imọ ẹsin Kristẹni, Micheal Nnadi jẹ ọkan alara awọn iṣekupani ọmọlẹyin Kristi to n peleke lẹnu ọjọ mẹta yii ni Naijiria.













