MMA: Àwọn èrò ní ìwà àjẹbánu ní kò jẹ́ kí Nàíjíríà ní ohun èèlò tó yẹ ní pápákọ̀ òfurufú

Oríṣun àwòrán, Others
Ijamba baalu ti ko waye lorilẹede Naijiria ni ọba oke ko wa yọ ninu rẹ nigba ti wọn dari awọn baalu to n ti oke okun bọ lọsan ọjọbọ oni, gba papakọ ofurufu ilẹ Ghana lọ lojiji, pe ki wọn lọ ba sibẹ.
Iroyin naa ni oju ọjọ ti ko dara ati ohun eelo igbalode kan to se pataki fun baalu lati ba ni papakọ ofurufu Muritala Muhammed tọjọ ti lọ lori rẹ, lo fa sababi bi wọn se dari awọn baalu naa lọ si papakọ ofurufu ilẹ Ghana.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho gba àwọn èèyàn Soka n‘Ibadan sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ onílẹ̀ tó wá ṣọṣẹ́
- Ẹ san ₦200,000 fún Sowore lórí bí ẹ ṣe ń fi ẹjọ́ falẹ̀ - Iléẹjọ́ pàṣẹ fún ìjọba
- Buhari, èyí to fí ogún ọdún pilẹ̀ wèrè lórí ètò ààbò Nàìjíríà tó gẹ́ - Bishop Kukah
- "Òògùn ni wọ́n fi bò mí lójú tí mo fi bá ara mi láàrin àwọn ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn"
- Na òṣìṣẹ́ Amotekun, ko san ₦250,000 owó ìjìyà, ko sì tún fi ẹ̀wọ̀n oṣù kan jura
- Wọ́n yìnbọn pa àwọn tó fipá bá ọmọ ọdún 12 lòpọ̀ ní gbangba lẹyin ìdájọ́
- Ajínigbé méjì kàgbákò lásìkò tí wọ́n fẹ́ ẹ́ já ọmọ gbà lọ́wọ́ ìyá rẹ̀ l'Ondo
A gbọ pe lara awọn baalu ilẹ okeere ti wọn pasẹ fun lati dori kọ papakọ ofurufu Ghana ni Baalu ilẹ Gẹẹsi, British Airways to n bọ lati London, baalu Delta to n bọ lati orilẹede Amerika ati baalu Emirates to n bọ lati Dubai.

Oríṣun àwòrán, Others
ọkan lara awọn ero to wa ninu baalu ilẹ Gẹẹsi, Olayiwola Zaid ni ko si ohun eelo igbalode tiyoo gbalẹmọ fun baalu lati ba, lo fa sababi, to si nira fun baalu awọn lati ba nitori pe o tobi pupọ, bi o tilẹ jẹ pe awọn baalu miran ba ni Eko laisi ewu.
O ni gbogbo awọn ero to wa ninu baalu naa ni aya awsn ko ja, ti skan awsn si balẹ lasiko tisẹlẹ abanilẹru naa n waye, ti awọn ko si gbo awakọ baalu tabi awọn osisẹ lẹnu titi to fi balẹ.

Oríṣun àwòrán, Others
Gbogbo ero ti isẹlẹ naa kan ni ẹnu wa n ya pe ki lo de ti papakọ ofurufu bii Muritala Muhammed ko fi ni awọn ẹrọ igbalode to yẹ fun baalu lati gbera ati lati ba silẹ.
" O ya mi lẹnu pe nitori ọyẹ lasan lasan, baalu ko le ba si Naijiria, nigba to jẹ pe awọn orilẹede miran ti oju ọjọ wọn buru jai, ti yinyin si maa n bọ, n faaye gba baalu lati ba. Eyi safihan bi iwa ajẹbanu se ba ọrọ aje Naijiria jẹ, to si n fa aago idagbasoke wa sẹyin, titi to fi kan papakọ ofurufu ilẹ wa."
Awakọ baalu naa ni o nira fun ohun lati riran daada pẹlu bi oju ọjọ se ri, ti Naijiria ko si ni ẹrọ igbalode to lee seranwọ lati fi balẹ, bẹẹ si ni baalu to balẹ bẹẹ lọjọ Isẹgun ana bajẹ ni.













