Ilaro Poly: Ààrẹ ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ṣọ́ọ́ṣì ni òun ń lọ, àmọ́ òun tó bára òun nínú igbó fún ìbúra ẹgbẹ́ awo

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọ nile ẹkọ gbogbonse Poly ti Ilaro, Adegboye Olatunji, ti aṣiri tu nijooni pe o wa ninu ẹgbẹ okunkun ti salaye pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ni wọn fi oogun mu oun lati darapọ mọ wọn.
Olatunji, lasiko ti olu ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Ogun n safihan rẹ pẹlu awọn afurasi bii mẹtadinlọgọrin miran fun oniruuru ẹsun to nii se pẹlu iwa sise ẹgbẹ okunkun, ifiyajẹni, ipaniyan ati idigunjale eyi to waye ni olu ileesẹ ọlọpa ni Eleweran, lo ti sọ bẹẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wọ́n yìnbọn pa àwọn tó fipá bá ọmọ ọdún 12 lòpọ̀ ní gbangba lẹyin ìdájọ́
- Ajínigbé méjì kàgbákò lásìkò tí wọ́n fẹ́ ẹ́ já ọmọ gbà lọ́wọ́ ìyá rẹ̀ l'Ondo
- Àwọn ǹkan ti ọ̀pọ̀ ko mọ nípa Baba Suwe
- China ṣe àgbéjáde "App" tí ẹ lè fi mọ̀ bóyá ẹ súnmọ́ aláàrùn Coronavirus
- Obìnrin tó rè kọjá lójú pópó ló fà ìjàmbá ọkọ́ Osun
O fikun pe ni ile ijọsin ni oun nlọ lasiko ti oun ko mọ oun ti oun n se mọ, ti oun si ba ara oun ninu igbo pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ti wọn n sebura fun oun.
Aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọ naa ni asiko ibura naa ni awọn ọlọpa de, ti wọn si ko oun mọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun, bẹẹ ni oun kii se ọmọ ẹgbẹ okunkun amọ ko ye oun bi oun se ba ara oun ninu igbo fun ibura imulẹ.
"Ile ijọsin ni mo n lọ lọjọ Isinmi nilu Ilaro ni deede aago meje aarọ, koda ọga ileewe wa gan n lọ sile ijọsin naa, to si korira ohunkohun to ba jọ mọ iwa sise ẹgbẹ awo."
Bakan naa lo wa kede pe ọwọ tawọn alasẹ ileewe oun gba mu isẹlẹ yii ko dun mọ oun ninu nitori pe wọn ko se iwadi to yẹ lori rẹ.









