China ṣe àgbéjáde "App" tí ẹ lè fi mọ̀ bóyá ẹ súnmọ́ aláàrùn Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iye awọn to ku latari arun Coronavirus ti le ni ẹgbrun kan bayìí.
Nitori eyi, orilẹede China ti ṣe agbejade ẹrọ ori ayelujara kan (Aapu) ti eeyan le fi ṣayẹwo bi wọn ba wa ni sakani kiko arun coronavirus.
Ẹrọ asunmọni bi eti yìí ti wọn n pe ni 'close contact detector' yoo sọ fun ẹni to n lo o boya o ti wa ni tosii ẹni to ni tabi ti wọ́n fura si pe o ni arun naa.
Awọn ti wọn ti na ika pe wọn wa ni bebe ati ko arun yii ni wọn ti gba nimọran pe ki wọn duro nile ki wọn si kan si awọn eleto ilera agbegbe ti wọn wa.
- Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Afíríkà kan tí lùgbadì ààrùn Coronavirus ní Fásitì China
- Awọn ikọ BBC ṣe abẹwo si China nibi ti aarun Coronavirus ti n ja rain
- A ti gbáradì báyìí pẹ̀lú ibùdó tó lèé kápáa àyẹ̀wò ààrùn Coronavirus - Ileéṣẹ́ ètò ìlera Nàìjíríà
- A kò fẹ́ kẹ kó àwọn ọmọ wa tó wà ní China wálé, kò sí ìtọ́jú fún àrun Coronavirus níbí - Ilé aṣojú-ṣòfin
Igbesẹ imọ ẹrọ yii ṣafihan bi ijọba orilẹede China ṣe sunmọ gbigbogun ti aarun yii gbagba ati onka awọn ara orilẹede naa.
Lati le wadii, ohun ti eeyan ni lati ṣe ni ko ya aworan kan (QR Code) ti yoo sare fara han lori foonu wọn bi wọn ba ti beere fun Aapu naa.
Niwọn igba too ba ti fi orukọ silẹ pẹlu foonu rẹ sori Aapu naa, yoo bere fun orukọ ati nọmba idanimọ iwọ too fẹ lo o.
Pẹlu ifọwọsowọpọ ẹka ijọba mẹta ọtọtọ pẹlu ẹgbẹ awọn onimọ ẹrọ ni China ati pẹlu awọn nkan ti wọn lee nilo ti ẹka eto ilera ati irna pese fun wọn ni wọn fi gbe Aapu naa kalẹ gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Xinhua ṣe sọ ọ.
Loju awọn ara China, wọn ri igbesẹ yii gẹgẹ bi eyi ti o wulo gan fawọn eeyan. Wọn ni o jẹ oun elo alagbara to ṣagihan bi ẹrọ ayelujara ṣe le wulo fun ohun to dara.
Itumọ ti orilẹede China tilẹ fun sisunmọ ni ninu ọrọ kiko arun coronavirus yii ni yala:
- Awọn eeyan to jọ n ṣiṣẹ pọ, jọ wa ninu kilaasi kan naa tabi jọ gbe pọ ninu ile kan
- Awọn oṣiṣẹ eto ilera, awọn mọlẹbi tabi awn mii ti wọn ti fara kan awọn to ni arun naa ati awọn to n tọju wọn.
- Awọn ero tabi oṣiṣẹ ọkọ ofurufu, ọkọ oju irin atawọn ọna irina mii ti wọn ṣalabapade ẹni to ti ko arun ọhun.
Fun apẹrẹ, gbogbo awọn to n rinrinajo ofurufu to joko papọ lori ila bii mẹta ti eeyan to ni arun naa si wa laarin wọn koda to fi mọ oṣiṣẹ ọkọ ofurufu ni eeyan lee ri gẹgẹ bii pe wọn sun mọ ara wọn nigba ti wọn yoo ri awọn ero to ku gẹgẹ bi ẹni ti ko fi bẹẹ sunm alaarun yii pẹtipẹti.
To ba wa di inu awọn ọkọ oju irin to ni afẹfẹ amaratutu ninu, gbogbo ero ninu ọkọ kan naa atawọn oṣiṣẹ patapata ni kẹẹ ri pe wọn sun mọ ara wọn pẹtipẹti.













