Coronavirus: Ilé aṣojú-ṣòfin tako kíkó ọmọ Nàìjíríà wálé láti China

Oríṣun àwòrán, Twitter/House of Reps NGR
Ile aṣoju-ṣofin gbona janjan lọjọ Iṣẹgun nigba ti wọn jiroro lori aba lati ko awọn ọmọ Naijiria to wa lorilẹede China wale, nitori aarun coronavirus to n ran kaakiri lorilẹede naa, bi ina inu ọyẹ.
Ṣugbọn lẹyin ọ rẹyin, ile pada fẹnu ko, lati tako aba kiko awọn ọmọ Naijiria to wa ni China wale.
Ohun ti ile sọ ni pe, orilẹede China ni awọn irinṣẹ igbalode nile iwosan ti wọn le fi dena aarun coronavirus ju Naijiria lọ.
- A ti gbáradì báyìí pẹ̀lú ibùdó tó lèé kápáa àyẹ̀wò ààrùn Coronavirus - Ileéṣẹ́ ètò ìlera Nàìjíríà
- Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Afíríkà kan tí lùgbadì ààrùn Coronavirus ní Fásitì China
- 'Ẹ bá wa sọ fún Sanwoolu kó dárí jì wá o, ìpinú tí wọ́n ṣe l'Eko kò m'ọ́gbọ́n wá rárá'
- Ìyàwó ilé lu ọmọ ọkọ rẹ̀ pa ní ìpínlẹ̀ Ogun
- Ọlọ́pàá fẹ̀sùn ìpànìyàn kan ìyawo olóòtú ilẹ̀ Lesotho pé ó pa ìyáálé rẹ̀
- Brexit: Ǹkan méje ti yóò yipada àti meje ti kò ni yi pada lẹ́yìn ti ilẹ Gẹ̀ẹ́si ti kuro labẹ EU
Bi adari ile, Femi Gbajabiamila se gbiyanju to lati parọwa fawọn aṣofin pe ki wọn tiẹ gbọ tẹnu aṣofin to mu aba naa wa, Benjamin Okezie, n ṣe ni wọn faake kọri, ti wọn ko si fun un lanfaani lati sọrọ.
Ohun to ya ọpọ lẹnu ni pe, awọn aṣofin meji mii to wa lara awọn to ṣagbatẹru aba naa kọ lati ṣe atilẹyin fun aṣofin Okezie nigba ti ọrọ naa di ede aiyede nile.

Oríṣun àwòrán, Twitter/House of Reps NGR
Ẹwẹ, aṣoju orilẹede China ni Naijiria, Zhou Pingjian sọ pe, ọgọta ọmọ Naijiria lakọsilẹ fihan pe o wa niluu Wuhan ti aarun coronavirus ti bẹrẹ gan.
Ṣugbọn Ọgbẹni Pingjian sọ pe, ko si ọmọ Naijiria kankan to tii lugbadi aarun coronavirus.








